O. Daf 68:5-7
O. Daf 68:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Baba awọn alainibaba ati onidajọ awọn opó, li Ọlọrun ni ibujoko rẹ̀ mimọ́. Ọlọrun mu ẹni-ofo joko ninu ile: o mu awọn ti a dè li ẹ̀wọn jade wá si irọra: ṣugbọn awọn ọlọtẹ ni ngbe inu ilẹ gbigbẹ. Ọlọrun, nigbati iwọ jade lọ niwaju awọn enia rẹ, nigbati iwọ nrìn lọ larin aginju.
O. Daf 68:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Baba àwọn aláìníbaba ati olùgbèjà àwọn opó ni Ọlọrun, ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́. Ọlọrun, olùpèsè ibùjókòó fún àlejò tí ó nìkan wà; ẹni tí ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra, ṣugbọn ó sì fi àwọn ọlọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ninu ilẹ̀ gbígbẹ. Ọlọrun, nígbà tí ò ń jáde lọ níwájú àwọn eniyan rẹ, nígbà tí ò ń yan la aṣálẹ̀ já
O. Daf 68:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́ Ọlọ́run gbé aláìlera kalẹ̀ nínú ìdílé, ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ. Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run, tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela.