ORIN DAFIDI 44:17-26

ORIN DAFIDI 44:17-26 YCE

Gbogbo nǹkan yìí ló ṣẹlẹ̀ sí wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbàgbé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹ majẹmu rẹ. Ọkàn wa kò pada lẹ́yìn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìlànà rẹ, sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko, o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀. Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa, tabi tí a bá bọ oriṣa, ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀? Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn. Ṣugbọn nítorí tìrẹ ni wọ́n fi ń pa wá tọ̀sán-tòru, tí a kà wá sí aguntan lọ́wọ́ alápatà. Para dà, OLUWA, kí ló dé tí o fi ń sùn? Jí gìrì! Má ta wá nù títí lae. Kí ló dé tí o fi ń fi ojú pamọ́? Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìpọ́njú ati ìnira wa? Nítorí pé àwọn ọ̀tá ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀; àyà wa sì lẹ̀ mọ́lẹ̀ típẹ́típẹ́. Gbéra nílẹ̀, kí o ràn wá lọ́wọ́! Gbà wá sílẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.