O. Daf 44:17-26
O. Daf 44:17-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo wọnyi li o de si wa; ṣugbọn awa kò gbagbe rẹ, bẹ̃li awa kò ṣe eke si majẹmu rẹ. Aiya wa kò pada sẹhin, bẹ̃ni ìrin wa kò yà kuro ni ipa tirẹ; Bi iwọ tilẹ ti fọ́ wa bajẹ ni ibi awọn ikõkò, ti iwọ si fi ojiji ikú bò wa mọlẹ. Bi o ba ṣepe awa gbagbe orukọ Ọlọrun wa, tabi bi awa ba nà ọwọ wa si ọlọrun ajeji; Njẹ Ọlọrun ki yio ri idi rẹ̀? nitori o mọ̀ ohun ìkọkọ aiya. Nitõtọ, nitori rẹ li a ṣe npa wa kú ni gbogbo ọjọ; a nkà wa si bi agutan fun pipa. Ji! ẽṣe ti iwọ nsùn, Oluwa? dide, máṣe ṣa wa tì kuro lailai. Ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́, ti iwọ si fi gbagbe ipọnju wa ati inira wa? Nitoriti a tẹri ọkàn wa ba sinu ekuru: inu wa dì mọ erupẹ ilẹ. Dide fun iranlọwọ wa, ki o si rà wa pada nitori ãnu rẹ.
O. Daf 44:17-26 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo nǹkan yìí ló ṣẹlẹ̀ sí wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbàgbé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹ majẹmu rẹ. Ọkàn wa kò pada lẹ́yìn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìlànà rẹ, sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko, o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀. Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa, tabi tí a bá bọ oriṣa, ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀? Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn. Ṣugbọn nítorí tìrẹ ni wọ́n fi ń pa wá tọ̀sán-tòru, tí a kà wá sí aguntan lọ́wọ́ alápatà. Para dà, OLUWA, kí ló dé tí o fi ń sùn? Jí gìrì! Má ta wá nù títí lae. Kí ló dé tí o fi ń fi ojú pamọ́? Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìpọ́njú ati ìnira wa? Nítorí pé àwọn ọ̀tá ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀; àyà wa sì lẹ̀ mọ́lẹ̀ típẹ́típẹ́. Gbéra nílẹ̀, kí o ràn wá lọ́wọ́! Gbà wá sílẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.
O. Daf 44:17-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa, síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀. Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá, ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú, tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀. Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn? Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́ a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa. Jí, OLúWA! Èéṣe tí ìwọ ń sùn? Dìde fúnra rẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé. Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú rẹ mọ́ tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa? Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku; ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀. Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́; rà wá padà nítorí ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.