ORIN DAFIDI 39:4-5

ORIN DAFIDI 39:4-5 YCE

“OLUWA, jẹ́ kí n mọ òpin ayé mi, ati ìwọ̀nba ọjọ́ ayé mi, kí n lè mọ̀ pé ayé mi ń sáré kọjá lọ.” Wò ó, o ti ṣe ọjọ́ mi ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ mélòó kan, ọjọ́ ayé mi kò sì tó nǹkankan ní ojú rẹ; dájúdájú, ọmọ eniyan dàbí afẹ́fẹ́ lásán.