O. Daf 39:4-5
O. Daf 39:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa, jẹ ki emi ki o mọ̀ opin mi ati ìwọn ọjọ mi, bi o ti ri; ki emi ki o le mọ̀ ìgbà ti mo ni nihin. Kiyesi i, iwọ ti sọ ọjọ mi dabi ibu atẹlẹwọ; ọjọ ori mi si dabi asan niwaju rẹ: nitõtọ olukuluku enia ninu ijoko rere rẹ̀ asan ni patapata.
Pín
Kà O. Daf 39O. Daf 39:4-5 Yoruba Bible (YCE)
“OLUWA, jẹ́ kí n mọ òpin ayé mi, ati ìwọ̀nba ọjọ́ ayé mi, kí n lè mọ̀ pé ayé mi ń sáré kọjá lọ.” Wò ó, o ti ṣe ọjọ́ mi ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ mélòó kan, ọjọ́ ayé mi kò sì tó nǹkankan ní ojú rẹ; dájúdájú, ọmọ eniyan dàbí afẹ́fẹ́ lásán.
Pín
Kà O. Daf 39O. Daf 39:4-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“OLúWA, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi, àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín. Ìwọ ti ṣe ayé mi bí ìbú àtẹ́lẹwọ́, ọjọ́ orí mi sì dàbí asán ní iwájú rẹ: Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.
Pín
Kà O. Daf 39