ORIN DAFIDI 33:4-22
ORIN DAFIDI 33:4-22 YCE
Nítorí ọ̀rọ̀ OLUWA dúró ṣinṣin; òtítọ́ sì ni ó fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. OLUWA fẹ́ràn òdodo ati ẹ̀tọ́; ayé kún fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ọ̀rọ̀ ni OLUWA fi dá ojú ọ̀run, èémí ẹnu rẹ̀ ni ó sì fi dá oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀. Ó wọ́ gbogbo omi òkun jọ bí òkìtì; ó pa gbogbo omi inú àwọn ibú pọ̀ bí ẹni pé ó rọ ọ́ sinu àgbá ńlá. Kí gbogbo ayé bẹ̀rù OLUWA, kí gbogbo aráyé dúró níwájú rẹ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù! Nítorí pé OLUWA sọ̀rọ̀, ayé wà; ó pàṣẹ, ayé sì dúró. OLUWA sọ ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè di asán; ó sì mú kí ètò àwọn eniyan já sófo. Ètò OLUWA wà títí lae, èrò ọkàn rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran. Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn, àní àwọn eniyan tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀! OLUWA bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run, ó rí gbogbo eniyan; láti orí ìtẹ́ rẹ̀ tí ó gúnwà sí, ó wo gbogbo aráyé. Òun ni ó dá ọkàn gbogbo wọn, tí ó sì ń mójútó gbogbo ìṣe wọn. Kì í ṣe pípọ̀ tí àwọn ọmọ ogun pọ̀ ní ń gba ọba là; kì í sì í ṣe ọ̀pọ̀ agbára níí gba jagunjagun là. Asán ni igbẹkẹle agbára ẹṣin ogun; kìí ṣe agbára tí ẹṣin ní, ló lè gbani là. Wò ó! OLUWA ń ṣọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àní àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, kí ó lè gba ọkàn wọn lọ́wọ́ ikú, kí ó sì mú wọn wà láàyè lákòókò ìyàn. Ọkàn wa ní ìrètí lọ́dọ̀ OLUWA; òun ni olùrànlọ́wọ́ ati ààbò wa. A láyọ̀ ninu rẹ̀, nítorí pé a gbẹ́kẹ̀lé orúkọ mímọ́ rẹ̀. OLUWA, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà lórí wa bí a ti gbẹ́kẹ̀lé ọ.



