O. Daf 33:4-22
O. Daf 33:4-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ti ọ̀rọ Oluwa tọ́: ati gbogbo iṣẹ rẹ̀ li a nṣe ninu otitọ. O fẹ otitọ ati idajọ: ilẹ aiye kún fun ãnu Oluwa. Nipa ọ̀rọ Oluwa li a da awọn ọrun, ati gbogbo ogun wọn nipa ẽmí ẹnu rẹ̀. O gbá awọn omi okun jọ bi ẹnipe òkiti kan: o tò ibu jọ ni ile iṣura. Ki gbogbo aiye ki o bẹ̀ru Oluwa: ki gbogbo araiye ki o ma wà ninu ẹ̀ru rẹ̀. Nitori ti o sọ̀rọ, o si ti ṣẹ; o paṣẹ, o si duro ṣinṣin. Oluwa mu ìmọ awọn orilẹ-ède di asan: o mu arekereke awọn enia ṣaki. Imọ Oluwa duro lailai, ìro inu rẹ̀ lati irandiran. Ibukún ni fun orilẹ-ède na, Ọlọrun ẹniti Oluwa iṣe; ati awọn enia na ti o ti yàn ṣe ini rẹ̀. Oluwa wò lati ọrun wá, o ri gbogbo ọmọ enia. Lati ibujoko rẹ̀ o wò gbogbo araiye. O ṣe aiya wọn bakanna; o kiyesi gbogbo iṣẹ wọn. Kò si ọba kan ti a ti ọwọ ọ̀pọ ogun gba silẹ: kò si alagbara kan ti a fi agbara pupọ̀ gba silẹ. Ohun asan li ẹṣin fun igbala: bẹ̃ni kì yio fi agbara nla rẹ̀ gbàni silẹ. Kiye si i, oju Oluwa mbẹ lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, lara awọn ti nreti ninu ãnu rẹ̀; Lati gba ọkàn wọn la lọwọ ikú, ati lati pa wọn mọ́ lãye ni igba ìyan. Ọkàn wa duro de Oluwa: on ni iranlọwọ wa ati asà wa. Nitori ti ọkàn wa yio yọ̀ niti rẹ̀, nitori ti awa ti gbẹkẹle orukọ rẹ̀ mimọ́. Ki ãnu rẹ, Oluwa, ki o wà lara wa, gẹgẹ bi awa ti nṣe ireti rẹ.
O. Daf 33:4-22 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ọ̀rọ̀ OLUWA dúró ṣinṣin; òtítọ́ sì ni ó fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. OLUWA fẹ́ràn òdodo ati ẹ̀tọ́; ayé kún fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ọ̀rọ̀ ni OLUWA fi dá ojú ọ̀run, èémí ẹnu rẹ̀ ni ó sì fi dá oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀. Ó wọ́ gbogbo omi òkun jọ bí òkìtì; ó pa gbogbo omi inú àwọn ibú pọ̀ bí ẹni pé ó rọ ọ́ sinu àgbá ńlá. Kí gbogbo ayé bẹ̀rù OLUWA, kí gbogbo aráyé dúró níwájú rẹ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù! Nítorí pé OLUWA sọ̀rọ̀, ayé wà; ó pàṣẹ, ayé sì dúró. OLUWA sọ ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè di asán; ó sì mú kí ètò àwọn eniyan já sófo. Ètò OLUWA wà títí lae, èrò ọkàn rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran. Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn, àní àwọn eniyan tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀! OLUWA bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run, ó rí gbogbo eniyan; láti orí ìtẹ́ rẹ̀ tí ó gúnwà sí, ó wo gbogbo aráyé. Òun ni ó dá ọkàn gbogbo wọn, tí ó sì ń mójútó gbogbo ìṣe wọn. Kì í ṣe pípọ̀ tí àwọn ọmọ ogun pọ̀ ní ń gba ọba là; kì í sì í ṣe ọ̀pọ̀ agbára níí gba jagunjagun là. Asán ni igbẹkẹle agbára ẹṣin ogun; kìí ṣe agbára tí ẹṣin ní, ló lè gbani là. Wò ó! OLUWA ń ṣọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àní àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, kí ó lè gba ọkàn wọn lọ́wọ́ ikú, kí ó sì mú wọn wà láàyè lákòókò ìyàn. Ọkàn wa ní ìrètí lọ́dọ̀ OLUWA; òun ni olùrànlọ́wọ́ ati ààbò wa. A láyọ̀ ninu rẹ̀, nítorí pé a gbẹ́kẹ̀lé orúkọ mímọ́ rẹ̀. OLUWA, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà lórí wa bí a ti gbẹ́kẹ̀lé ọ.
O. Daf 33:4-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nítorí pé ọ̀rọ̀ OLúWA dúró ṣinṣin, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́. Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú OLúWA. Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ OLúWA ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀. Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò; ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo. Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù OLúWA: jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin. OLúWA ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán; ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í. Ìgbìmọ̀ OLúWA dúró títí ayérayé, àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni. Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí OLúWA jẹ́ tirẹ̀, àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀. OLúWA wò láti ọ̀run wá; Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn. Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́ Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà, ó sì kíyèsi ìṣe wọn. A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun; kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀. Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun; bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀. Wò ó, ojú OLúWA wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin. Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn. Ọkàn wa dúró de OLúWA; òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa. Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀, nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́. Kí àánú rẹ, OLúWA, kí ó wà lára wa, àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.