ORIN DAFIDI 138:1-3

ORIN DAFIDI 138:1-3 YCE

N óo máa yìn ọ́ tọkàntọkàn OLUWA, lójú àwọn oriṣa ni n óo máa kọrin ìyìn sí ọ. Ní ìtẹríba, n óo kọjú sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ, n óo sì máa yin orúkọ rẹ, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ, nítorí pé o gbé ọ̀rọ̀ rẹ ati orúkọ rẹ ga ju ohunkohun lọ. Ní ọjọ́ tí mo ké pè ọ́, o dá mi lóhùn, o sì fún mi ní agbára kún agbára.