O. Daf 138:1-3
O. Daf 138:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI o ma yìn ọ tinu-tinu mi gbogbo; niwaju awọn oriṣa li emi o ma kọrin iyìn si ọ. Emi o ma gbadura siha tempili mimọ́ rẹ, emi o si ma yìn orukọ rẹ nitori iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ; nitori iwọ gbé ọ̀rọ rẹ ga jù gbogbo orukọ rẹ lọ. Li ọjọ ti mo kepè, iwọ da mi lohùn, iwọ si fi ipa mu mi lara le li ọkàn mi.
O. Daf 138:1-3 Yoruba Bible (YCE)
N óo máa yìn ọ́ tọkàntọkàn OLUWA, lójú àwọn oriṣa ni n óo máa kọrin ìyìn sí ọ. Ní ìtẹríba, n óo kọjú sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ, n óo sì máa yin orúkọ rẹ, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ, nítorí pé o gbé ọ̀rọ̀ rẹ ati orúkọ rẹ ga ju ohunkohun lọ. Ní ọjọ́ tí mo ké pè ọ́, o dá mi lóhùn, o sì fún mi ní agbára kún agbára.
O. Daf 138:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo; níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ. Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀ èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ; nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ. Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn, ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.