Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ,
èyí tí ó fún mi ní ìrètí.
Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé:
ìlérí rẹ mú mi wà láàyè.
Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi,
ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀.
Mo ranti òfin rẹ àtijọ́,
OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀.
Inú mi á máa ru,
nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú,
tí wọn ń rú òfin rẹ.
Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ,
lákòókò ìrìn àjò mi láyé.
Mo ranti orúkọ rẹ lóru;
OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́:
Èyí ni ìṣe mi:
Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́.
OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní;
mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́.
Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ,
ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi,
mo yipada sí ìlànà rẹ;
mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́.
Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi,
n kò ní gbàgbé òfin rẹ.
Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́,
nítorí ìlànà òdodo rẹ.
Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí,
àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́.
OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ,
gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé,
nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ.
Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ;
ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ.
OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀,
ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́.
Ọkàn wọn ti yigbì,
ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ.
Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani,
ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ.
Òfin rẹ níye lórí fún mi,
ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ.
Ìwọ ni o mọ mí, ìwọ ni o dá mi,
fún mi ní òye kí n lè kọ́ òfin rẹ.
Inú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yóo máa dùn
nígbà tí wọ́n bá rí mi,
nítorí pé mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.
OLUWA, mo mọ̀ pé ìdájọ́ rẹ tọ̀nà,
ati pé lórí ẹ̀tọ́ ni o pọ́n mi lójú.
Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa tù mí ninu,
gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe fún èmi, iranṣẹ rẹ.
Ṣàánú mi, kí n lè wà láàyè,
nítorí pé òfin rẹ ni ìdùnnú mi.
Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn onigbeeraga,
nítorí wọ́n ṣe àrékérekè sí mi láìnídìí;
ní tèmi, n óo máa ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.
Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ tọ̀ mí wá,
kí wọ́n lè mọ òfin rẹ.
Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé,
kí ojú má baà tì mí.
Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi;
ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.
Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,
níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ.
Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?”
Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì,
sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ.
Èmi iranṣẹ rẹ yóo ti dúró pẹ́ tó?
Nígbà wo ni ìwọ óo dájọ́ fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi?
Àwọn onigbeeraga ti gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,
àní, àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́.
Gbogbo òfin rẹ ló dájú;
ràn mí lọ́wọ́, nítorí wọ́n ń fi ìwà èké ṣe inúnibíni mi.
Wọ́n fẹ́rẹ̀ pa mí run láyé,
ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀.
Dá ẹ̀mí mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
kí n lè máa mú gbogbo àṣẹ rẹ ṣẹ.
OLUWA, títí lae ni ọ̀rọ̀ rẹ fìdí múlẹ̀ lọ́run.
Òtítọ́ rẹ wà láti ìrandíran;
o ti fi ìdí ayé múlẹ̀, ó sì dúró.
Ohun gbogbo wà gẹ́gẹ́ bí ìlànà rẹ, títí di òní,
nítorí pé iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn.
Bí kò bá jẹ́ pé òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi,
ǹ bá ti ṣègbé ninu ìpọ́njú.
Lae, n kò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ,
nítorí pé, nípasẹ̀ wọn ni o fi mú mi wà láyé.
Ìwọ ni o ni mí, gbà mí;
nítorí pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
Àwọn eniyan burúkú ba dè mí,
wọ́n fẹ́ pa mí run,
ṣugbọn mò ń ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.
Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán,
àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin.
Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ!
Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru.
Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo.
Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ,
nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò.
Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ,
nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
N kò rin ọ̀nà ibi kankan,
kí n lè pa òfin rẹ mọ́.
N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ,
nítorí pé o ti kọ́ mi.
Ọ̀rọ̀ rẹ dùn mọ́ mi pupọ,
ó dùn ju oyin lọ.
Nípa ẹ̀kọ́ rẹ ni mo fi ní òye,
nítorí náà mo kórìíra gbogbo ìwà èké.