ORIN DAFIDI 112:4-6

ORIN DAFIDI 112:4-6 YCE

Ìmọ́lẹ̀ yóo tàn fún olódodo ninu òkùnkùn, olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, aláàánú ni, a sì máa ṣòdodo. Yóo máa dára fún ẹni tí ó bá lójú àánú, tí ó sì ń yáni ní nǹkan, tí ó ń ṣe ẹ̀tọ́ ní gbogbo ọ̀nà. A kò ní ṣí olódodo ní ipò pada lae, títí ayé ni a óo sì máa ranti rẹ̀.