O. Daf 112:4-6
O. Daf 112:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Fun ẹni-diduro-ṣinṣin ni imọlẹ mọ́ li òkunkun: olore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o si ṣe olododo. Enia rere fi oju-rere hàn, a si wínni: imoye ni yio ma fi là ọ̀na iṣẹ rẹ̀. Nitoriti a kì yio yi i nipò pada lailai: olododo yio wà ni iranti titi aiye.
O. Daf 112:4-6 Yoruba Bible (YCE)
Ìmọ́lẹ̀ yóo tàn fún olódodo ninu òkùnkùn, olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, aláàánú ni, a sì máa ṣòdodo. Yóo máa dára fún ẹni tí ó bá lójú àánú, tí ó sì ń yáni ní nǹkan, tí ó ń ṣe ẹ̀tọ́ ní gbogbo ọ̀nà. A kò ní ṣí olódodo ní ipò pada lae, títí ayé ni a óo sì máa ranti rẹ̀.
O. Daf 112:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn: olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo. Ènìyàn rere fi ojúrere hàn, a sì wínni; ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀. Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé: olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.