ÌWÉ ÒWE 27:17-22

ÌWÉ ÒWE 27:17-22 YCE

Bí irin ti ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀. Ẹni tí ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóo rí èso rẹ̀ jẹ, ẹni tí ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóo gba ìyìn rẹ̀. Bí omi tíí fi bí ojú ẹni ti rí han ni, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn eniyan ń fi irú ẹni tí eniyan jẹ́ hàn. Ìparun ati isà òkú kò lè ní ìtẹ́lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ náà ni ojú eniyan, kì í ní ìtẹ́lọ́rùn. Iná ni a fi ń dán wúrà ati fadaka wò, ìyìn ni a fi ń dán eniyan wò. Wọn ì báà ju òmùgọ̀ sinu odó, kí wọn fi ọmọ odó gún un pọ̀ mọ́ ọkà, ẹnìkan kò lè gba ìwà òmùgọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.