Owe 27:17-22
Owe 27:17-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Irin a ma pọn irin: bẹ̃li ọkunrin ipọn oju ọrẹ́ rẹ̀. Ẹnikẹni ti o tọju igi-ọpọtọ yio jẹ eso rẹ̀; bẹ̃li ẹniti o duro tì oluwa rẹ̀ li a o buyì fun. Bi oju ti ikò oju li omi, bẹ̃li aiya enia si enia. Ipò-okú ati iparun kì ikún, bẹ̃ni kì isu oju enia. Bi koro fun fadaka, ati ileru fun wura, bẹ̃li enia si iyìn rẹ̀. Bi iwọ tilẹ fi ọmọri-odó gún aṣiwère ninu odo larin alikama, wère rẹ̀ kì yio fi i silẹ.
Owe 27:17-22 Yoruba Bible (YCE)
Bí irin ti ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀. Ẹni tí ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóo rí èso rẹ̀ jẹ, ẹni tí ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóo gba ìyìn rẹ̀. Bí omi tíí fi bí ojú ẹni ti rí han ni, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn eniyan ń fi irú ẹni tí eniyan jẹ́ hàn. Ìparun ati isà òkú kò lè ní ìtẹ́lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ náà ni ojú eniyan, kì í ní ìtẹ́lọ́rùn. Iná ni a fi ń dán wúrà ati fadaka wò, ìyìn ni a fi ń dán eniyan wò. Wọn ì báà ju òmùgọ̀ sinu odó, kí wọn fi ọmọ odó gún un pọ̀ mọ́ ọkà, ẹnìkan kò lè gba ìwà òmùgọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.
Owe 27:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí irin tí ń pọ́n irin mú bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú. Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èso rẹ̀ ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá. Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn. Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí. Iná fún fàdákà iná ìléru fún wúrà, ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà. Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó, fi ọmọ odó gún un bí èlùbọ́ ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.