ÌWÉ ÒWE 2:1-9

ÌWÉ ÒWE 2:1-9 YCE

Ọmọ mi, bí o bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́, tí o bá ń tẹ́tí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n, tí o sì fi ọkàn sí òye, bí o bá kígbe tí o tọrọ òye tí ó jinlẹ̀, tí o gbóhùn sókè tí o bèèrè ìmọ̀, bí o bá wá ọgbọ́n bí ẹni ń wá fadaka, tí o sì wá a bí ẹni ń wá ìṣúra tí a pamọ́, nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLUWA yóo yé ọ. O óo sì rí ìmọ̀ Ọlọrun. Nítorí OLUWA níí fún ni ní ọgbọ́n, ẹnu rẹ̀ sì ni òye ati ìmọ̀ ti ń wá. Ó fún àwọn tí wọn dúró ṣinṣin ní ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n, òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ó ń tọ́ wọn sí ìdájọ́ òtítọ́, ó sì ń pa ọ̀nà àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìtumọ̀ òdodo ati ẹ̀tọ́ yóo yé ọ ati àìṣe ojuṣaaju, ati gbogbo ọ̀nà rere.