ÌWÉ ÒWE 2

2
Èrè Tó Wà ninu Ọgbọ́n
1Ọmọ mi, bí o bá gba ọ̀rọ̀ mi,
tí o sì pa òfin mi mọ́,
2tí o bá ń tẹ́tí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n,
tí o sì fi ọkàn sí òye,
3bí o bá kígbe tí o tọrọ òye tí ó jinlẹ̀,
tí o gbóhùn sókè tí o bèèrè ìmọ̀,
4bí o bá wá ọgbọ́n bí ẹni ń wá fadaka,
tí o sì wá a bí ẹni ń wá ìṣúra tí a pamọ́,
5nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLUWA yóo yé ọ.
O óo sì rí ìmọ̀ Ọlọrun.
6Nítorí OLUWA níí fún ni ní ọgbọ́n,#Ọgb 9:10; Sir 1:1
ẹnu rẹ̀ sì ni òye ati ìmọ̀ ti ń wá.
7Ó fún àwọn tí wọn dúró ṣinṣin ní ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n,
òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́.
8Ó ń tọ́ wọn sí ìdájọ́ òtítọ́,
ó sì ń pa ọ̀nà àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ mọ́.
9Nígbà náà ni ìtumọ̀ òdodo ati ẹ̀tọ́ yóo yé ọ
ati àìṣe ojuṣaaju, ati gbogbo ọ̀nà rere.
10Nítorí ọgbọ́n yóo wọnú ọkàn rẹ,
ìmọ̀ yóo sì tu ẹ̀mí rẹ lára,
11ọgbọ́n inú yóo máa ṣọ́ ọ,
òye yóo sì máa dáàbò bò ọ́,
12yóo máa gbà ọ́ lọ́wọ́ ibi ṣíṣe,
ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn,
13àwọn tí wọ́n ti kọ ọ̀nà òdodo sílẹ̀
tí wọn sì ń rìn ninu òkùnkùn;
14àwọn tí wọn ń yọ̀ ninu ìwà ibi
tí wọ́n sì ní inú dídùn sí ìyapa ibi;
15àwọn tí ọ̀nà wọn wọ́,
tí wọ́n kún fún ìwà àrékérekè.
16A óo gbà ọ́ lọ́wọ́ obinrin oníṣekúṣe,
àní lọ́wọ́ obinrin onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀.
17Ẹni tí ó kọ ọkọ àárọ̀ rẹ̀ sílẹ̀,
tí ó sì gbàgbé majẹmu Ọlọrun rẹ̀.
18Ẹni tí ilé rẹ̀ rì sinu ìparun,
tí ọ̀nà rẹ̀ sì wà ninu ọ̀fìn isà òkú.
19Kò sí ẹni tí ó tọ̀ ọ́ lọ, tí ó pada rí,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í tún pada sí ọ̀nà ìyè.
20Nítorí náà, máa rìn ní ọ̀nà àwọn eniyan rere,
sì máa bá àwọn olódodo rìn.
21Nítorí àwọn tí wọ́n dúró ṣinṣin ni wọn yóo máa gbé ilẹ̀ náà,
àwọn olóòótọ́ inú ni yóo máa wà níbẹ̀,
22ṣugbọn a óo pa ẹni ibi run lórí ilẹ̀ náà,
a óo sì fa alárèékérekè tu kúrò níbẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 2: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa