FILIPI 2:16-18

FILIPI 2:16-18 YCE

tí ẹ sì ń polongo ọ̀rọ̀ ìyè. Èyí ni yóo jẹ́ ìṣògo fún mi ní ọjọ́ tí Kristi bá dé, nítorí yóo hàn pé iré-ìje tí mò ń sá kì í ṣe lásán, ati pé aápọn tí mo ti ṣe kò já sí òfo. Ṣugbọn bí a bá fi mí ṣe ohun ìrúbọ ati ohun èèlò ninu ìsìn nítorí igbagbọ yín, ó dùn mọ́ mi, n óo sì máa yọ̀ pẹlu gbogbo yín. Nítorí náà, kí inú yín kí ó máa dùn, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀.