MATIU 24:30-35

MATIU 24:30-35 YCE

Àmì Ọmọ-Eniyan yóo wá yọ ní ọ̀run. Gbogbo àwọn ẹ̀yà ayé yóo figbe ta, wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí ó ń bọ̀ lórí ìkùukùu ní ọ̀run pẹlu agbára ògo ńlá. Yóo wá rán angẹli rẹ̀ pẹlu fèrè ńlá, wọn yóo kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé; àní láti ìkangun ọ̀run kan dé ìkangun keji. “Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọnyi, kí ẹ̀yin náà mọ̀ pé àkókò súnmọ́ tòsí, ó ti dé ẹnu ọ̀nà. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn eniyan ìran yìí kò ní tíì kú tán títí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹlẹ̀. Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ.

Àwọn fídíò fún MATIU 24:30-35