Mat 24:30-35
Mat 24:30-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana li àmi Ọmọ-enia yio si fi ara hàn li ọrun; nigbana ni gbogbo ẹya aiye yio kãnu, nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla. Yio si rán awọn angẹli rẹ̀ ti awọn ti ohùn ipè nla, nwọn o si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun ọrun kan lọ de ikangun keji. Njẹ ẹ kọ́ owe lara igi ọpọtọ; nigbati ẹká rẹ̀ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ̀ pe igba ẹ̃rùn sunmọ etile: Gẹgẹ bẹ̃ li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri gbogbo nkan wọnyi, ki ẹ mọ̀ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun. Lõtọ ni mo wi fun nyin, iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ. Ọrun on aiye yio rekọjá, ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja.
Mat 24:30-35 Yoruba Bible (YCE)
Àmì Ọmọ-Eniyan yóo wá yọ ní ọ̀run. Gbogbo àwọn ẹ̀yà ayé yóo figbe ta, wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí ó ń bọ̀ lórí ìkùukùu ní ọ̀run pẹlu agbára ògo ńlá. Yóo wá rán angẹli rẹ̀ pẹlu fèrè ńlá, wọn yóo kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé; àní láti ìkangun ọ̀run kan dé ìkangun keji. “Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọnyi, kí ẹ̀yin náà mọ̀ pé àkókò súnmọ́ tòsí, ó ti dé ẹnu ọ̀nà. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn eniyan ìran yìí kò ní tíì kú tán títí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹlẹ̀. Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ.
Mat 24:30-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
“Nígbà náà ni àmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá. Yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú ohùn ìpè ńlá, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti ọ̀run jọ. “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti ń yọ tuntun tí ó bá sì ń ru ewé, ẹ̀yin mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí i tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìpadàbọ̀ mi dé tán lẹ́yìn ìlẹ̀kùn. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò kọjá títí tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ. Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.