ẸKÚN JEREMAYA 2:1-6

ẸKÚN JEREMAYA 2:1-6 YCE

Ẹ wò bí OLUWA ti fi ibinu fi ìkùukùu bo Sioni mọ́lẹ̀. Ó ti wọ́ ògo Israẹli lu láti òkè ọ̀run sórí ilẹ̀ ayé; kò tilẹ̀ ranti àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀. OLUWA ti pa gbogbo ibùgbé Jakọbu run láìsí àánú. Ó ti fi ibinu wó ibi ààbò Juda lulẹ̀. Ó ti rẹ ìjọba ati àwọn aláṣẹ rẹ̀ sílẹ̀, ó fi àbùkù kàn wọ́n. Ó ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀, pa àwọn alágbára Israẹli; ó kọ̀, kò ràn wọ́n lọ́wọ́, nígbà tí àwọn ọ̀tá dojú kọ wọ́n. Ó jó àwọn ọmọ Jakọbu bí iná, ó sì pa gbogbo ohun tí wọn ní run. Ó kẹ́ ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá, ó múra bí aninilára. Gbogbo ògo wa ló parun lójú wa, ó sì tú ibinu rẹ̀ jáde bí iná, ninu àgọ́ Sioni. OLUWA ṣe bí ọ̀tá, ó ti pa Israẹli run. Ó ti pa gbogbo ààfin rẹ̀ run, ó sọ àwọn ibi ààbò rẹ̀ di àlàpà ó sì sọ ọ̀fọ̀ ati ẹkún Juda di pupọ. Ó wó àgọ́ rẹ̀ lulẹ̀, bí ìgbà tí eniyan wó ahéré oko. Ó pa gbogbo ibi tí wọ́n ti ń ṣe àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ run. OLUWA ti fi òpin sí àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, ati ọjọ́ ìsinmi ní Sioni. Ó sì ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀, kọ ọba ati alufaa sílẹ̀.