Ẹk. Jer 2:1-6
Ẹk. Jer 2:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
BAWO li Oluwa ti fi awọsanma bo ọmọbinrin Sioni ni ibinu rẹ̀! ti o sọ ẹwa Israeli kalẹ lati oke ọrun wá si ilẹ, ti kò si ranti apoti-itisẹ rẹ̀ li ọjọ ibinu rẹ̀! Oluwa ti gbe gbogbo ibugbe Jakobu mì, kò si da a si: o ti wó ilu-odi ọmọbinrin Juda lulẹ, ninu irunu rẹ̀ o ti lù wọn bolẹ: o ti sọ ijọba na ati awọn ijoye rẹ̀ di alaimọ́. O ti ke gbogbo iwo Israeli kuro ninu ibinu gbigbona rẹ̀: o ti fà ọwọ ọtun rẹ̀ sẹhin niwaju ọta, o si jo gẹgẹ bi ọwọ iná ninu Jakobu ti o jẹrun yikakiri. O ti fà ọrun rẹ̀ gẹgẹ bi ọta: o duro, o mura ọwọ ọtun rẹ̀ gẹgẹ bi aninilara, o si pa gbogbo ohun didara ti oju fẹ iri ni agọ ọmọbinrin Sioni, o dà irunu rẹ̀ jade bi iná. Oluwa jẹ gẹgẹ bi ọta: o ti gbe Israeli mì, o ti gbe gbogbo ãfin rẹ̀ mì: o ti pa ilu olodi rẹ̀ run o si ti fi ibanujẹ lori ibanujẹ fun ọmọbinrin Juda. O si ti wó ọgba rẹ̀ lulẹ, gẹgẹ bi àgbala: o ti pa ibi apejọ rẹ̀ run: Oluwa ti mu ki a gbagbe ajọ-mimọ́ ati ọjọ isimi ni Sioni, o ti fi ẹ̀gan kọ̀ ọba ati alufa silẹ ninu ikannu ibinu rẹ̀.
Ẹk. Jer 2:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ wò bí OLUWA ti fi ibinu fi ìkùukùu bo Sioni mọ́lẹ̀. Ó ti wọ́ ògo Israẹli lu láti òkè ọ̀run sórí ilẹ̀ ayé; kò tilẹ̀ ranti àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀. OLUWA ti pa gbogbo ibùgbé Jakọbu run láìsí àánú. Ó ti fi ibinu wó ibi ààbò Juda lulẹ̀. Ó ti rẹ ìjọba ati àwọn aláṣẹ rẹ̀ sílẹ̀, ó fi àbùkù kàn wọ́n. Ó ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀, pa àwọn alágbára Israẹli; ó kọ̀, kò ràn wọ́n lọ́wọ́, nígbà tí àwọn ọ̀tá dojú kọ wọ́n. Ó jó àwọn ọmọ Jakọbu bí iná, ó sì pa gbogbo ohun tí wọn ní run. Ó kẹ́ ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá, ó múra bí aninilára. Gbogbo ògo wa ló parun lójú wa, ó sì tú ibinu rẹ̀ jáde bí iná, ninu àgọ́ Sioni. OLUWA ṣe bí ọ̀tá, ó ti pa Israẹli run. Ó ti pa gbogbo ààfin rẹ̀ run, ó sọ àwọn ibi ààbò rẹ̀ di àlàpà ó sì sọ ọ̀fọ̀ ati ẹkún Juda di pupọ. Ó wó àgọ́ rẹ̀ lulẹ̀, bí ìgbà tí eniyan wó ahéré oko. Ó pa gbogbo ibi tí wọ́n ti ń ṣe àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ run. OLUWA ti fi òpin sí àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, ati ọjọ́ ìsinmi ní Sioni. Ó sì ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀, kọ ọba ati alufaa sílẹ̀.
Ẹk. Jer 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báwo ni Olúwa ṣe bo ọmọbìnrin Sioni pẹ̀lú àwọsánmọ̀ ìbínú rẹ̀! Ó sọ ògo Israẹli kalẹ̀ Láti ọ̀run sí ayé; kò rántí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀. Láìní àánú ni Olúwa gbé ibùgbé Jakọbu mì; nínú ìrunú rẹ̀, ni ó wó ibi gíga ọmọbìnrin Juda lulẹ̀. Ó ti mú ìjọba àti àwọn ọmọ-aládé ọkùnrin lọ sínú ilẹ̀ ní àìlọ́wọ̀. Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó ké gbogbo ìwo Israẹli. Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò nígbà tí àwọn ọ̀tá dé. Ó run ní Jakọbu bí ọ̀wọ́-iná ní àgọ́ àwọn ọmọbìnrin Sioni. Ó na ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múra Bí ti ọ̀tá tí ó ti parun ó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná sórí àgọ́ ọmọbìnrin Sioni. Olúwa dàbí ọ̀tá; ó gbé Israẹli mì. Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mì ó pa ibi gíga rẹ̀ run. Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin Juda. Ó mú ìparun bá ibi mímọ́, ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run. OLúWA ti mú Sioni gbàgbé àjọ̀dún tí a yàn àti ọ̀sẹ̀ tí ó yàn; nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run ọba àti olórí àlùfáà.