JOṢUA 6:26-27

JOṢUA 6:26-27 YCE

Joṣua bá gégùn-ún nígbà náà pé, “Ẹni ìfibú OLUWA ni ẹnikẹ́ni tí ó bá dìde láti tún ìlú Jẹriko kọ́. Àkọ́bí ẹni tí ó bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ yóo kú, àbíkẹ́yìn rẹ̀ yóo kú nígbà tí ó bá gbé ìlẹ̀kùn ibodè rẹ̀ ró.” OLUWA wà pẹlu Joṣua, òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo ilẹ̀ náà.