Joṣ 6:26-27
Joṣ 6:26-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Joṣua si gégun li akokò na wipe, Egún ni fun ọkunrin na niwaju OLUWA ti yio dide, ti yio si kọ ilu Jeriko yi: pẹlu ikú akọ́bi rẹ̀ ni yio fi pilẹ rẹ̀, ati pẹlu ikú abikẹhin rẹ̀ ni yio fi gbé ilẹkun ibode rẹ̀ ró. Bẹ̃ni OLUWA wà pẹlu Joṣua; okikí rẹ̀ si kàn ká gbogbo ilẹ na.
Joṣ 6:26-27 Yoruba Bible (YCE)
Joṣua bá gégùn-ún nígbà náà pé, “Ẹni ìfibú OLUWA ni ẹnikẹ́ni tí ó bá dìde láti tún ìlú Jẹriko kọ́. Àkọ́bí ẹni tí ó bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ yóo kú, àbíkẹ́yìn rẹ̀ yóo kú nígbà tí ó bá gbé ìlẹ̀kùn ibodè rẹ̀ ró.” OLUWA wà pẹlu Joṣua, òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo ilẹ̀ náà.
Joṣ 6:26-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkókò náà Joṣua sì búra pé; “Ègún ni fún ẹni náà níwájú OLúWA tí yóò dìde, tí yóò sì tún ìlú Jeriko kọ́: “Pẹ̀lú ikú àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni yóò fi pilẹ̀ rẹ̀; ikú àbíkẹ́yìn rẹ̀ ní yóò fi gbé ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ ró.” Bẹ́ẹ̀ ni OLúWA wà pẹ̀lú Joṣua; òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.