JOBU 6:14-30

JOBU 6:14-30 YCE

“Ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣàánú ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò ní ìbẹ̀rù Olodumare. Ṣugbọn, ẹ̀yin arakunrin mi, ẹlẹ́tàn ni yín, bíi odò àgbàrá tí ó yára kún, tí ó sì tún yára gbẹ, tí yìnyín bo odò náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣókùnkùn, tí yìnyín ńláńlá sì farapamọ́ sibẹ, ṣugbọn ní àkókò ooru, wọn a yọ́, bí ilẹ̀ bá ti gbóná, wọn a sì gbẹ. Àwọn oníṣòwò tí ń lo ràkúnmí yà kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n ń wá omi kiri wọ́n kiri títí wọ́n fi ṣègbé ninu aṣálẹ̀. Àwọn oníṣòwò Temani ń wò rá rà rá, àwọn ọ̀wọ́ èrò Ṣeba sì dúró pẹlu ìrètí. Ìrètí wọn di òfo nítorí wọ́n ní ìdánilójú. Wọ́n dé ibi tí odò wà tẹ́lẹ̀, ṣugbọn òfo ni wọ́n bá. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí sí mi nisinsinyii. Ẹ rí ìdààmú mi, ẹ̀rù bà yín. Ǹjẹ́ mo tọrọ ẹ̀bùn lọ́wọ́ yín? Tabi mo bẹ̀ yín pé kí ẹ mú ninu owó yín, kí ẹ fi san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí mi? Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín pé kí ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá; tabi pé kí ẹ rà mí pada kúrò lọ́wọ́ aninilára? “Ó dára, mo gbọ́, ẹ wá kọ́ mi, ẹ ṣàlàyé ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ fún mi; n óo sì dákẹ́ n óo tẹ́tí sílẹ̀. Lóòótọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní agbára, ṣugbọn kí ni ẹ̀ ń bá mi wí lé lórí. Ẹ rò pé mò ń fi ọ̀rọ̀ ṣòfò lásán ni? Kí ni ẹ̀ ń dásí ọ̀rọ̀ èmi onírora sí? Ẹ tilẹ̀ lè ṣẹ́ gègé lórí ọmọ òrukàn, ẹ sì lè díye lé ọ̀rẹ́ yín. “Ẹ gbọ́, ẹ wò mí dáradára, nítorí n kò ní purọ́ níwájú yín. Mo bẹ̀ yín, ẹ dúró bẹ́ẹ̀, kí ẹ má baà ṣẹ̀. Ẹ dúró bẹ́ẹ̀, nítorí n kò lẹ́bi. Ṣé ẹ rò pé mò ń parọ́ ni? Àbí n kò mọ nǹkan burúkú yàtọ̀?