Job 6:14-30

Job 6:14-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹniti aya rẹ̀ yọ́ danu tan ni a ba ma ṣãnu fun lati ọdọ ọrẹ rẹ̀ wá, ki o má kọ̀ ibẹru Olodumare silẹ̀. Awọn ará mi ṣẹ̀tan bi odò ṣolõ, bi iṣàn gburu omi odò ṣolõ, nwọn ṣàn kọja lọ. Ti o dúdu nitori omi didì, ati nibiti òjo didì gbe lùmọ si. Nigbakũgba ti nwọn ba gboná, nwọn a si yọ́ ṣanlọ, nigbati õrùn ba mú, nwọn si gbẹ kurò ni ipò wọn. Iya ọ̀na wọn a si yipada sapakan, nwọn goke si ibi asan, nwọn si run. Ẹgbẹ ogun Tema nwoye, awọn ọwọ́-èro Seba duro de wọn. Nwọn dãmu, nitoriti nwọn ni abá; nwọn debẹ̀, nwọn si dãmu. Njẹ nisisiyi, ẹnyin dabi wọn; ẹnyin ri irẹ̀silẹ mi, aiya si fò nyin. Emi ha wipe, ẹ mu ohun fun mi wá, tabi pe, ẹ bun mi ni ẹ̀bun ninu ohun ini nyin? Tabi, ẹ gbà mi li ọwọ ọ̀ta nì, tabi, ẹ rà mi padà kuro lọwọ alagbara nì! Ẹ kọ́ mi, emi o si pa ẹnu mi mọ́; ki ẹ si mu mi moye ibiti mo gbe ti ṣìna. Wo! bi ọ̀rọ otitọ ti li agbara to! ṣugbọn kini aròye ibawi nyin jasi? Ẹnyin ṣebi ẹ o ba ọ̀rọ ati ohùn ẹnu ẹniti o taku wi, ti o dabi afẹfẹ. Ani ẹnyin ṣẹ́ gege fun alainibaba, ẹnyin si da iye le ọrẹ nyin. Nitorina ki eyi ki o tó fun nyin: ẹ ma wò mi! nitoripe o hàn gbangba pe: li oju nyin ni emi kì yio ṣeke. Emi bẹ̀ nyin, ẹ pada, ki o má ṣe jasi ẹ̀ṣẹ: ani ẹ si tun pada, are mi mbẹ ninu ọ̀ran yi. Aiṣedede ha wà li ahọn mi? njẹ itọwò ẹnu mi kò kuku le imọ̀ ohun ti o burujù?

Job 6:14-30 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣàánú ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò ní ìbẹ̀rù Olodumare. Ṣugbọn, ẹ̀yin arakunrin mi, ẹlẹ́tàn ni yín, bíi odò àgbàrá tí ó yára kún, tí ó sì tún yára gbẹ, tí yìnyín bo odò náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣókùnkùn, tí yìnyín ńláńlá sì farapamọ́ sibẹ, ṣugbọn ní àkókò ooru, wọn a yọ́, bí ilẹ̀ bá ti gbóná, wọn a sì gbẹ. Àwọn oníṣòwò tí ń lo ràkúnmí yà kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n ń wá omi kiri wọ́n kiri títí wọ́n fi ṣègbé ninu aṣálẹ̀. Àwọn oníṣòwò Temani ń wò rá rà rá, àwọn ọ̀wọ́ èrò Ṣeba sì dúró pẹlu ìrètí. Ìrètí wọn di òfo nítorí wọ́n ní ìdánilójú. Wọ́n dé ibi tí odò wà tẹ́lẹ̀, ṣugbọn òfo ni wọ́n bá. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí sí mi nisinsinyii. Ẹ rí ìdààmú mi, ẹ̀rù bà yín. Ǹjẹ́ mo tọrọ ẹ̀bùn lọ́wọ́ yín? Tabi mo bẹ̀ yín pé kí ẹ mú ninu owó yín, kí ẹ fi san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí mi? Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín pé kí ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá; tabi pé kí ẹ rà mí pada kúrò lọ́wọ́ aninilára? “Ó dára, mo gbọ́, ẹ wá kọ́ mi, ẹ ṣàlàyé ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ fún mi; n óo sì dákẹ́ n óo tẹ́tí sílẹ̀. Lóòótọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní agbára, ṣugbọn kí ni ẹ̀ ń bá mi wí lé lórí. Ẹ rò pé mò ń fi ọ̀rọ̀ ṣòfò lásán ni? Kí ni ẹ̀ ń dásí ọ̀rọ̀ èmi onírora sí? Ẹ tilẹ̀ lè ṣẹ́ gègé lórí ọmọ òrukàn, ẹ sì lè díye lé ọ̀rẹ́ yín. “Ẹ gbọ́, ẹ wò mí dáradára, nítorí n kò ní purọ́ níwájú yín. Mo bẹ̀ yín, ẹ dúró bẹ́ẹ̀, kí ẹ má baà ṣẹ̀. Ẹ dúró bẹ́ẹ̀, nítorí n kò lẹ́bi. Ṣé ẹ rò pé mò ń parọ́ ni? Àbí n kò mọ nǹkan burúkú yàtọ̀?

Job 6:14-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá, kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀? Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé bí ìṣàn omi odò, wọ́n sàn kọjá lọ. Tí ó dúdú nítorí omi dídì, àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́. Nígbàkúgbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ, nígbà tí oòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn. Àwọn oníṣòwò yà kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run. Ẹgbẹ́ oníṣòwò Tema ń wá omi, àwọn oníṣòwò Ṣeba ń dúró dè wọ́n ní ìrètí. Wọ́n káàárẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e; wọ́n dé bẹ̀, wọ́n sì dààmú. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin dàbí wọn; ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí. Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá, tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín? Tàbí, ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni, tàbí, ẹ rà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì’? “Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́ kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti ṣìnà. Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tó ṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbáwí yín jásí? Ẹ̀yin ṣè bí ẹ tún ọ̀rọ̀ mi ṣe àti ohùn ẹnu tí ó dàbí afẹ́fẹ́ ṣe àárẹ̀. Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba, ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín. “Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín. Ẹ má wò mi! Nítorí pé ó hàn gbangba pé: Ní ojú yín ni èmi kì yóò ṣèké. Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀; àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí. Àìṣedéédéé ha wà ní ahọ́n mi? Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù?