Jobu bá dáhùn pé, “Bí ó bá ṣeéṣe láti wọn ìbànújẹ́ mi, tí a bá sì le gbé ìdààmú mi lé orí ìwọ̀n, ìbá wúwo ju yanrìn etí òkun lọ. Ìdí nìyí tí mo fi ń fi ìtara sọ̀rọ̀. Ọfà Olodumare wọ̀ mí lára, oró rẹ̀ sì mú mi. Ọlọrun kó ìpayà bá mi. Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó a máa ké tí ó bá rí koríko jẹ? Àbí mààlúù a máa dún tí ó bá ń wo oúnjẹ rẹ̀ nílẹ̀? Ǹjẹ́ ohun tí kò dùn ṣe é jẹ láì fi iyọ̀ sí i? Tabi, adùn wo ní ń bẹ ninu funfun ẹyin? Irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ kì í wù mí í jẹ, Ìríra ni jíjẹ rẹ̀ jẹ́ fún mi. “Ìbá ti dára tó, kí Ọlọrun mú ìbéèrè mi ṣẹ, kí ó fún mi ní ohun tí ọkàn mi ń fẹ́. Àní, kí ó wó mi mọ́lẹ̀, kí ó mú mi, kí ó pa mí dànù. Yóo jẹ́ ìtùnú fún mi; n óo sì láyọ̀ ninu ọpọlọpọ ìrora, nítorí pé n kò sẹ́ ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́. Agbára wo ni mo ní, tí mo fi lè tún máa wà láàyè? Kí sì ni ìrètí mi, tí n óo fi tún máa ní sùúrù? Agbára mi ha rí bí ti òkúta bí? Àbí ẹran ara mi jẹ́ idẹ? Nítòótọ́, n kò ní agbára mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní olùrànlọ́wọ́.
Kà JOBU 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOBU 6:1-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò