“Ògòǹgò lu ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ninu ọláńlá rẹ̀,
ṣugbọn kò lè fò bí ẹyẹ àkọ̀?
Ó yé ẹyin rẹ̀ sórí ilẹ̀,
kí ooru ilẹ̀ lè mú wọn,
ó gbàgbé pé ẹnìkan le tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ kí wọn sì fọ́,
ati pé ẹranko ìgbẹ́ lè fọ́ wọn.
Ògòǹgò kò náání àwọn ọmọ rẹ̀,
ó ń ṣe sí wọn bí ẹni pé kì í ṣe òun ló bí wọn,
kò bìkítà bí wahala rẹ̀ tilẹ̀ já sí asán;
nítorí pé Ọlọrun kò fún un ní ọgbọ́n ati òye.
Ṣugbọn nígbà tí ó bá ṣetán ati sáré,
a máa fi ẹṣin ati ẹni tí ó gùn ún ṣe yẹ̀yẹ́.
“Ṣé ìwọ ni o fún ẹṣin lágbára,
tí o sì fi agbára ṣe gọ̀gọ̀ sí i lọ́rùn?
Ṣé ìwọ lò ń mú kí ó máa ta pọ́nún bí eṣú,
tí kíké rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù?
Ó fẹsẹ̀ walẹ̀ ní àfonífojì,
ó yọ̀ ninu agbára rẹ̀,
ó sì jáde lọ sí ojú ogun.
Kò mọ ẹ̀rù, ọkàn rẹ̀ kì í rẹ̀wẹ̀sì,
bẹ́ẹ̀ ni kì í sá fún idà.
Ó gbé apó ọfà sẹ́yìn, tí ń mì pẹkẹpẹkẹ, pẹlu ọ̀kọ̀
tí ń kọ mànà, ati apata.
Ó ń fi ẹnu họlẹ̀ pẹlu ìgboyà ati ìwàǹwára,
nígbà tí ipè dún, ara rẹ̀ kò balẹ̀.
Nígbà tí fèrè dún, ó kọ, ‘Hàáà!’
Ó ń gbóòórùn ogun lókèèrè,
ó ń gbọ́ igbe ọ̀gágun tí ń pàṣẹ.
“Ṣé ìwọ lo kọ́ àwòdì bí a ti í fò,
tí ó fi na ìyẹ́ rẹ̀ sí ìhà gúsù?
Ṣé ìwọ ni o pàṣẹ fún idì láti fò lọ sókè,
tabi láti tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sórí òkè gíga?
Ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí òkè gíga-gíga,
ninu pàlàpálá àpáta.
Níbẹ̀ ni ó ti ń ṣọ́ ohun tí yóo pa,
ojú rẹ̀ a sì rí i láti òkèèrè réré.
Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa mu ẹ̀jẹ̀,
ibi tí òkú bá sì wà ni idì máa ń wà.”