Job 39:13-30
Job 39:13-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iyẹ abo-ogongo nfi ayọ̀ fì, iyẹ ati ihuhu rẹ̀ daradara ni bi? Kò ri bẹ̃? o fi ẹyin rẹ̀ silẹ-yilẹ, a si mu wọn gbona ninu ekuru. Ti o si gbagbe pe, ẹsẹ le itẹ wọn fọ, tabi pe, ẹranko igbẹ le itẹ wọn fọ: Kò ni ãjo si awọn ọmọ rẹ̀ bi ẹnipe nwọn kì iṣe tirẹ̀, asan ni iṣẹ rẹ̀ laibẹru: Nitoripe Ọlọrun dù u li ọgbọ́n, bẹ̃ni kò si fi ipin oye fun u. Nigbati o gbe ara soke, o gàn ẹṣin ati ẹlẹṣin. Iwọ li o fi agbara fun ẹṣin, iwọ li o fi gọ̀gọ wọ ọrùn rẹ̀ li aṣọ? Iwọ le imu u fò soke bi ẹlẹnga, ogo ẽmi imu rẹ̀ ni ẹ̀ru-nla. O fi ẹsẹ halẹ ninu aporo, o si yọ̀ si agbara rẹ̀; o nlọ jade lati pade awọn ahamọra ogun. O fi oju kekere wò ẹ̀ru, aiya kò si fò o; bẹ̃ni kì isi ipada sẹhin kuro lọwọ idà. Lọdọ rẹ̀ ni apo-ọfa nmi pẹkẹpẹkẹ, ati ọ̀kọ didan ati apata. On fi kikoro oju ati ibinu nla gbe ilẹ mì, bẹ̃li on kò si gbagbọ pe, iro ipè ni. O wi ni igba ipè pe, Ha! Ha! o si gborùn ogun lokere rere: ãrá awọn balogun ati ihó àyọ wọn. Awodi a ma ti ipa ọgbọ́n rẹ fò soke, ti o si nà iyẹ apa rẹ̀ siha gusu? Idì a ma fi aṣẹ rẹ fò lọ soke, ki o si lọ itẹ ìtẹ rẹ̀ si oke giga? O ngbe o si wọ̀ li ori apata, lori palapala okuta ati ibi ori oke. Lati ibẹ lọ ni ima wá ọdẹ kiri, oju rẹ̀ si riran li òkere rere. Awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu a ma mu ẹ̀jẹ, nibiti okú ba gbe wà, nibẹ li on wà pẹlu.
Job 39:13-30 Yoruba Bible (YCE)
“Ògòǹgò lu ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ninu ọláńlá rẹ̀, ṣugbọn kò lè fò bí ẹyẹ àkọ̀? Ó yé ẹyin rẹ̀ sórí ilẹ̀, kí ooru ilẹ̀ lè mú wọn, ó gbàgbé pé ẹnìkan le tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ kí wọn sì fọ́, ati pé ẹranko ìgbẹ́ lè fọ́ wọn. Ògòǹgò kò náání àwọn ọmọ rẹ̀, ó ń ṣe sí wọn bí ẹni pé kì í ṣe òun ló bí wọn, kò bìkítà bí wahala rẹ̀ tilẹ̀ já sí asán; nítorí pé Ọlọrun kò fún un ní ọgbọ́n ati òye. Ṣugbọn nígbà tí ó bá ṣetán ati sáré, a máa fi ẹṣin ati ẹni tí ó gùn ún ṣe yẹ̀yẹ́. “Ṣé ìwọ ni o fún ẹṣin lágbára, tí o sì fi agbára ṣe gọ̀gọ̀ sí i lọ́rùn? Ṣé ìwọ lò ń mú kí ó máa ta pọ́nún bí eṣú, tí kíké rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù? Ó fẹsẹ̀ walẹ̀ ní àfonífojì, ó yọ̀ ninu agbára rẹ̀, ó sì jáde lọ sí ojú ogun. Kò mọ ẹ̀rù, ọkàn rẹ̀ kì í rẹ̀wẹ̀sì, bẹ́ẹ̀ ni kì í sá fún idà. Ó gbé apó ọfà sẹ́yìn, tí ń mì pẹkẹpẹkẹ, pẹlu ọ̀kọ̀ tí ń kọ mànà, ati apata. Ó ń fi ẹnu họlẹ̀ pẹlu ìgboyà ati ìwàǹwára, nígbà tí ipè dún, ara rẹ̀ kò balẹ̀. Nígbà tí fèrè dún, ó kọ, ‘Hàáà!’ Ó ń gbóòórùn ogun lókèèrè, ó ń gbọ́ igbe ọ̀gágun tí ń pàṣẹ. “Ṣé ìwọ lo kọ́ àwòdì bí a ti í fò, tí ó fi na ìyẹ́ rẹ̀ sí ìhà gúsù? Ṣé ìwọ ni o pàṣẹ fún idì láti fò lọ sókè, tabi láti tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sórí òkè gíga? Ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí òkè gíga-gíga, ninu pàlàpálá àpáta. Níbẹ̀ ni ó ti ń ṣọ́ ohun tí yóo pa, ojú rẹ̀ a sì rí i láti òkèèrè réré. Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa mu ẹ̀jẹ̀, ibi tí òkú bá sì wà ni idì máa ń wà.”
Job 39:13-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
“Ìwọ ni yóò ha fi ìyẹ́ dáradára fún ọ̀kín bí, tàbí ìyẹ́ àti ìhùhù bo ògòǹgò? Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀, a sì mú wọn gbóná nínú ekuru; tí ó sì gbàgbé pé, ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́, tàbí pé ẹranko igbó lè tẹ̀ wọ́n fọ́. Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bí ẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀; asán ni iṣẹ́ rẹ̀ láìní ìbẹ̀rù; nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un. Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin. “Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí, tàbí ṣé ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ? Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà? Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá. Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀; ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun. Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fò ó; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà. Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹkẹpẹkẹ, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta. Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbé ilé mi, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbà á gbọ́ pé, ìró ìpè ni. Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà! Ó sì gbóhùn ogun lókèèrè réré, igbe àwọn balógun àti ìhó ayọ̀ ogun wọn. “Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fò sókè, tí ó sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúúsù? Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè, kí ó sì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga? Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta, lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè. Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ kiri, ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré. Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀, níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú.”