JOBU 12:13-25

JOBU 12:13-25 YCE

Ọlọrun ló ni ọgbọ́n ati agbára, tirẹ̀ ni ìmọ̀ràn ati ìmọ̀. Ohun tí Ọlọrun bá wó lulẹ̀, ta ló lè tún un kọ́? Tí ó bá ti eniyan mọ́lé, ta ló lè tú u sílẹ̀? Bí ó bá dáwọ́ òjò dúró, ọ̀gbẹlẹ̀ a dé, bí ó bá sí rọ òjò, omi a bo ilẹ̀. Òun ló ni agbára ati ọgbọ́n, òun ló ni ẹni tí ń tan ni jẹ, òun náà ló ni ẹni tí à ń tàn. Ó pa ọgbọ́n mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu, ó sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀. Ó tú àwọn tí àwọn ọba dè mọ́lẹ̀, ó sì so ẹ̀wọ̀n mọ́ àwọn ọba gan-an nídìí. Ó rẹ àwọn alufaa sílẹ̀, ó sì gba agbára lọ́wọ́ àwọn alágbára. Ó pa àwọn agbẹnusọ lẹ́nu mọ́, ó gba ìmọ̀ àwọn àgbààgbà. Ó dójúti àwọn olóyè, ó tú àmùrè àwọn alágbára. Ó mú ohun òkùnkùn wá sí ìmọ́lẹ̀, ó sì tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn biribiri. Òun níí sọ àwọn orílẹ̀-èdè di ńlá, òun náà níí sìí tún pa wọ́n run: Òun níí kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ, òun náà níí sì ń tú wọn ká. Ó gba ìmọ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjòyè ní gbogbo ayé, ó sì sọ wọ́n di alárìnká ninu aṣálẹ̀, níbi tí ọ̀nà kò sí. Wọ́n ń táràrà ninu òkùnkùn, ó sì mú kí wọ́n máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí.