Job 12:13-25
Job 12:13-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Pẹlu rẹ̀ (Ọlọrun) li ọgbọ́n ati agbarà, on ni ìmọ ati oye, Kiyesi i, o biwó, a kò si le igbe ró mọ́, o se enia mọ́, kò si sí iṣisilẹ̀ kan. Kiyesi i, o da awọn omi duro, nwọn si gbẹ, o si rán wọn jade, nwọn si ṣẹ bo ilẹ aiye yipo. Pẹlu rẹ̀ li agbara ati ọgbọ́n, ẹniti nṣìna ati ẹniti imu ni ṣìna tirẹ̀ ni nwọn iṣe. O mu awọn igbimọ̀ lọ nihoho, a si sọ awọn onidajọ di wère. O tu ide ọba, o si fi àmure gbà wọn li ọ̀ja. O mu awọn alufa lọ nihoho, o si tẹ ori awọn alagbara bá. O mu ọ̀rọ-ẹnu ẹni-igbẹkẹle kuro, o si ra awọn àgbàgbà ni iye. O bù ẹ̀gan lu awọn ọmọ-alade, o si tú àmure awọn alagbara. O hudi ohun ti o sigbẹ jade lati inu òkunkun wá, o si mu ojiji ikú jade wá sinu imọlẹ̀. On a mu orilẹ-ède bi si i, a si run wọn, on a sọ orilẹ-ède di nla, a si tun ṣẹ́ wọn kù. On a gbà aiya olú awọn enia aiye, a si ma mu wọn wọ́ kakiri ninu iju nibiti ọ̀na kò si. Nwọn a ma fi ọwọ ta ilẹ ninu òkunkun laisi imọlẹ, on a si ma mu wọn tàse irin bi ọmuti.
Job 12:13-25 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun ló ni ọgbọ́n ati agbára, tirẹ̀ ni ìmọ̀ràn ati ìmọ̀. Ohun tí Ọlọrun bá wó lulẹ̀, ta ló lè tún un kọ́? Tí ó bá ti eniyan mọ́lé, ta ló lè tú u sílẹ̀? Bí ó bá dáwọ́ òjò dúró, ọ̀gbẹlẹ̀ a dé, bí ó bá sí rọ òjò, omi a bo ilẹ̀. Òun ló ni agbára ati ọgbọ́n, òun ló ni ẹni tí ń tan ni jẹ, òun náà ló ni ẹni tí à ń tàn. Ó pa ọgbọ́n mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu, ó sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀. Ó tú àwọn tí àwọn ọba dè mọ́lẹ̀, ó sì so ẹ̀wọ̀n mọ́ àwọn ọba gan-an nídìí. Ó rẹ àwọn alufaa sílẹ̀, ó sì gba agbára lọ́wọ́ àwọn alágbára. Ó pa àwọn agbẹnusọ lẹ́nu mọ́, ó gba ìmọ̀ àwọn àgbààgbà. Ó dójúti àwọn olóyè, ó tú àmùrè àwọn alágbára. Ó mú ohun òkùnkùn wá sí ìmọ́lẹ̀, ó sì tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn biribiri. Òun níí sọ àwọn orílẹ̀-èdè di ńlá, òun náà níí sìí tún pa wọ́n run: Òun níí kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ, òun náà níí sì ń tú wọn ká. Ó gba ìmọ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjòyè ní gbogbo ayé, ó sì sọ wọ́n di alárìnká ninu aṣálẹ̀, níbi tí ọ̀nà kò sí. Wọ́n ń táràrà ninu òkùnkùn, ó sì mú kí wọ́n máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí.
Job 12:13-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ti Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára: Òun ló ni ìmọ̀ àti òye. Kíyèsi i, ó bì wó, a kò sì lè gbe ró mọ́; Ó sé ènìyàn mọ́, kò sì sí ìtúsílẹ̀ kan. Kíyèsi i, ó dá àwọn omi dúró, wọ́n sì gbẹ; Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì ṣẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo. Tìrẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun; Ẹni tí ń ṣìnà àti ẹni tí ń mú ni ṣìnà, tirẹ̀ ni wọ́n ń ṣe. Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòhò, A sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀. Ó tú ìdè ọba, Ó sì fi àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já. Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòhò, Ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba. Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò, Ó sì ra àwọn àgbàgbà ní iyè. Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́lá, Ó sì tú àmùrè àwọn alágbára. Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá, Ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀. Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n; Òun a sọ orílẹ̀-èdè di ńlá, a sì tún ṣẹ̀ wọn kù. Òun a gba òye àwọn olórí àwọn ènìyàn aráyé, A sì máa mú wọn rin kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí. Wọn a máa fi ọwọ́ ta ilẹ̀ nínú òkùnkùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀, Òun a sì máa mú ìrìn ìsìn wọn bí ọ̀mùtí.