JOBU 1:8-11

JOBU 1:8-11 YCE

OLUWA tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí ẹni tí ó jẹ́ olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé, ati pé ó bẹ̀rù èmi OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú?” Satani dáhùn pé, “Ṣé lásán ni Jobu bẹ̀rù ìwọ Ọlọrun ni? Ṣebí nígbà gbogbo ni ò ń dáàbò bo òun ati àwọn ará ilé rẹ̀, ati gbogbo ohun tí ó ní. Ò ń bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, o sì sọ ohun ìní rẹ̀ di pupọ. Ǹjẹ́, ìwọ mú gbogbo nǹkan wọnyi kúrò wò, o óo rí i pé yóo sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.”