Job 1:8-11
Job 1:8-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa si sọ fun Satani pe, Iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ li aiye, ọkunrin ti iṣe olõtọ, ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu. Nigbana ni Satani dá Oluwa lohùn wipe: Jobu ha bẹ̀ru Oluwa li asan bi? Iwọ kò ha ti sọgbà yi i ká, ati yi ile rẹ̀ ati yi ohun ti o ni ká ni iha gbogbo? Iwọ busi iṣẹ ọwọ rẹ̀, ohunọ̀sin rẹ̀ si npọsi i ni ilẹ. Njẹ nawọ rẹ nisisiyi, ki o si fi tọ́ ohun gbogbo ti o ni; bi kì yio si bọhùn li oju rẹ.
Job 1:8-11 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí ẹni tí ó jẹ́ olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé, ati pé ó bẹ̀rù èmi OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú?” Satani dáhùn pé, “Ṣé lásán ni Jobu bẹ̀rù ìwọ Ọlọrun ni? Ṣebí nígbà gbogbo ni ò ń dáàbò bo òun ati àwọn ará ilé rẹ̀, ati gbogbo ohun tí ó ní. Ò ń bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, o sì sọ ohun ìní rẹ̀ di pupọ. Ǹjẹ́, ìwọ mú gbogbo nǹkan wọnyi kúrò wò, o óo rí i pé yóo sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.”
Job 1:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì sọ fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòtítọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kórìíra ìwà búburú.” Nígbà náà ni Satani dá OLúWA lóhùn wí pé, “Jobu ha bẹ̀rù Ọlọ́run ní asán bí?” “Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùsi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ̀ si ní ilẹ̀. Ǹjẹ́, nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ni; bí kì yóò sì bọ́hùn ni ojú rẹ.”