JEREMAYA 5

5
1Máa sáré lọ, sáré bọ̀ ní àwọn òpópónà Jerusalẹmu,
wò yíká, kí o sì ṣàkíyèsí rẹ̀!
Wo àwọn gbàgede rẹ̀, bóyá o óo rí ẹnìkan,
tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo,
tí ó sì ń fẹ́ òtítọ́,
tí mo fi lè torí rẹ̀ dáríjì Jerusalẹmu.
2Lóòótọ́ ni wọ́n ń fi orúkọ mi búra pé, “Bí OLUWA tí ń bẹ,”
sibẹ èké ni ìbúra wọn.
3OLUWA, ṣebí òtítọ́ ni ò ń fẹ́?
Ò ń nà wọ́n ní pàṣán, ṣugbọn kò dùn wọ́n,
o tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́,
ṣugbọn wọn kò gbọ́ ìbáwí.
Ojú wọn ti dá, ó le koko,
wọ́n kọ̀, wọn kò ronupiwada.
4Nígbà náà ní mo wí lọ́kàn ara mi pé,
“Àwọn aláìní nìkan nìwọ̀nyí,
wọn kò gbọ́n;
nítorí wọn kò mọ ọ̀nà OLUWA,
ati òfin Ọlọrun wọn.
5N óo lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan pataki pataki,
n óo sì bá wọn sọ̀rọ̀;
nítorí àwọn mọ ọ̀nà OLUWA,
ati òfin Ọlọrun wọn.”
Ṣugbọn gbogbo wọn náà ni wọ́n ti fa àjàgà wọn dá,
tí wọ́n sì ti kọ àṣẹ ati àkóso OLUWA.
6Nítorí náà, kinniun inú igbó ni yóo wá kì wọ́n mọ́lẹ̀.
Ìkookò inú aṣálẹ̀ ni yóo wá jẹ wọ́n run.
Àmọ̀tẹ́kùn yóo ba dè wọ́n ní àwọn ìlú wọn,
tí ẹnikẹ́ni bá jáde ní ìlú,
yóo fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀,
nígbà pupọ ni wọ́n sì ti yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun.
7OLUWA bi Israẹli pé,
“Báwo ni mo ṣe lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn ọ́?
Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀,
wọ́n sì ti ń fi àwọn ohun tí kì í ṣe ọlọrun búra.
Nígbà tí mo bọ́ wọn ní àbọ́yó tán,
wọ́n ṣe àgbèrè,
wọ́n dà lọ sí ilé àwọn alágbèrè.
8Wọ́n dàbí akọ ẹṣin tí a kò tẹ̀ lọ́dàá, tí ó yó,
olukuluku wọn ń lé aya aládùúgbò rẹ̀ kiri.
9Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?
Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?
10Kọjá lọ láàrin ọgbà àjàrà rẹ̀ ní poro ní poro, kí o sì pa á run,
ṣugbọn má ṣe pa gbogbo rẹ̀ run tán.
Gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,
nítorí pé wọn kì í ṣe ti OLUWA.
11Nítorí pé ilé Israẹli ati ilé Juda ti ṣe alaiṣootọ sí mi.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Ọlọrun kọ Israẹli sílẹ̀
12Àwọn eniyan yìí ti sọ ọ̀rọ̀ èké nípa OLUWA,
wọ́n ní, “OLUWA kọ́! Kò ní ṣe nǹkankan;
ibi kankan kò ní dé bá wa,
bẹ́ẹ̀ ni a kò ní rí ogun tabi ìyàn.”
13Àwọn wolii yóo di àgbá òfo;
nítorí kò sí ọ̀rọ̀ OLUWA ninu wọn.
Bí wọ́n ti wí ni ọ̀rọ̀ yóo rí fún wọn.
14Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní,
“Nítorí ohun tí wọ́n sọ yìí,
wò ó, n óo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi di iná lẹ́nu rẹ.
N óo sì jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi dàbí igi,
iná yóo sì jó wọn run.
15Ẹ wò ó, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli,
mò ń mú orílẹ̀-èdè kan bọ̀ wá ba yín, láti ilẹ̀ òkèèrè,
tí yóo ba yín jà.
Láti ayé àtijọ́ ni orílẹ̀-èdè ọ̀hún ti wà,
orílẹ̀-èdè alágbára ni.
Ẹ kò gbọ́ èdè wọn,
ẹ kò sì ní mọ ohun tí wọ́n ń sọ.
16Apó ọfà wọn dàbí isà òkú tó yanu sílẹ̀,
alágbára jagunjagun ni gbogbo wọn.
17Wọn yóo jẹ yín ní oúnjẹ,
wọn yóo sì kó gbogbo ìkórè oko yín lọ,
wọn yóo run àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin.
Wọn yóo run ẹran ọ̀sìn yín,
ati àwọn mààlúù yín.
Wọn yóo run èso ọgbà àjàrà yín, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ yín.
Idà ni wọn yóo fi pa àwọn ìlú olódi yín tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé run.”
18OLUWA ní, “Ṣugbọn sibẹ, ní gbogbo àkókò yìí, n kò ní pa yín run patapata, 19nígbà tí àwọn eniyan bá bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí wa?’ Ẹ óo le dá wọn lóhùn pé bí ẹ ṣe kọ èmi OLUWA sílẹ̀, tí ẹ sì ń bọ oriṣa àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.”
Ọlọrun Kìlọ̀ fún Àwọn Eniyan Rẹ̀
20OLUWA ní, “Kéde rẹ̀ ní ilẹ̀ Jakọbu,
sì ṣe ìfilọ̀ rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda:
21Ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin òmùgọ̀, aláìlọ́gbọ́n,#Ais 6:9-10; Isi 12:2; Mak 8:18
ẹ̀yin tí ẹ lójú, ṣugbọn tí ẹ kò ríran;
ẹ létí, ṣugbọn tí ẹ kò gbọ́ràn.
22Ẹ̀rù mi kò tilẹ̀ bà yín?#Job 38: 8-11
Èmi OLUWA ni mò ń bi yín léèrè.
Ẹ wà níwájú mi ẹ kò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.
Èmi tí mo fi iyanrìn pààlà fún omi òkun,
tí òkun kò sì gbọdọ̀ rékọjá rẹ̀ títí ayé!
Bí ó tilẹ̀ ń ru sókè, kò lágbára kan,
kí ìgbì rẹ̀ máa hó yaya, kò lè kọjá ààlà náà.
23Ṣugbọn ọkàn ẹ̀yin eniyan wọnyi le, ọlọ̀tẹ̀ sì ni yín.
Ẹ ti yapa, ẹ sì ti ṣáko lọ.
24Ẹ kò sì rò ó lọ́kàn yín, kí ẹ wí pé:
‘Ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun wa,
tí ó ń fún wa ní òjò lákòókò rẹ̀,
ati òjò àkọ́rọ̀ ati àrọ̀kẹ́yìn;
OLUWA tí ó ń bá wa mú ọjọ́ ìkórè lọ́wọ́,
tí kì í jẹ́ kí àsìkò ìkórè ó yẹ̀.’
25Àìdára yín ti yí ìgbà wọnyi pada,
ẹ̀ṣẹ̀ yín ti dínà ohun rere fun yín.
26“Àwọn eniyan burúkú wà láàrin àwọn eniyan mi,
wọ́n ń dọdẹ eniyan bí ẹni dọdẹ ẹyẹ,
wọ́n dẹ tàkúté, wọ́n fi ń mú eniyan.
27Ilé wọn kún fún ìwà ọ̀dàlẹ̀,
bíi kùùkú tí ó kún fún ẹyẹ.
Nítorí èyí, wọ́n di eniyan ńlá,
wọ́n di olówó,
28wọ́n sanra, ara wọn sì ń dán.
Ṣugbọn iṣẹ́ ibi wọn kò ní ààlà.
Wọn kìí dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún aláìníbaba,
kí ó lè rí ẹ̀tọ́ rẹ̀ gbà;
wọn kò sì jẹ́ gbèjà aláìní,
kí wọ́n bá a dáàbò bo ẹ̀tọ́ rẹ̀ nílé ẹjọ́.
29Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?
Kí n má gbẹ̀san ara mi, lára irú orílẹ̀-èdè yìí?
30Nǹkan burúkú tó yani lẹ́nu,
ní ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà:
31Àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké,
àwọn alufaa ń sọ ọ̀rọ̀ èké àwọn wolii di òfin,
àwọn eniyan mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.
Ṣugbọn kí ni wọ́n óo ṣe nígbà tí òpin bá dé?”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JEREMAYA 5: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀