1
JEREMAYA 5:22
Yoruba Bible
YCE
Ẹ̀rù mi kò tilẹ̀ bà yín? Èmi OLUWA ni mò ń bi yín léèrè. Ẹ wà níwájú mi ẹ kò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Èmi tí mo fi iyanrìn pààlà fún omi òkun, tí òkun kò sì gbọdọ̀ rékọjá rẹ̀ títí ayé! Bí ó tilẹ̀ ń ru sókè, kò lágbára kan, kí ìgbì rẹ̀ máa hó yaya, kò lè kọjá ààlà náà.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí JEREMAYA 5:22
2
JEREMAYA 5:1
Máa sáré lọ, sáré bọ̀ ní àwọn òpópónà Jerusalẹmu, wò yíká, kí o sì ṣàkíyèsí rẹ̀! Wo àwọn gbàgede rẹ̀, bóyá o óo rí ẹnìkan, tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo, tí ó sì ń fẹ́ òtítọ́, tí mo fi lè torí rẹ̀ dáríjì Jerusalẹmu.
Ṣàwárí JEREMAYA 5:1
3
JEREMAYA 5:31
Àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, àwọn alufaa ń sọ ọ̀rọ̀ èké àwọn wolii di òfin, àwọn eniyan mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn kí ni wọ́n óo ṣe nígbà tí òpin bá dé?”
Ṣàwárí JEREMAYA 5:31
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò