JAKỌBU 2:6-8

JAKỌBU 2:6-8 YCE

Ṣugbọn ẹ̀ ń kẹ́gàn mẹ̀kúnnù. Ṣebí àwọn ọlọ́rọ̀ níí máa fìtínà yín, tí wọn máa ń fà yín lọ sí kóòtù! Ṣebí àwọn ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí orúkọ rere tí a fi ń pè yín! Ẹ̀ ń ṣe dáradára tí ẹ bá pa òfin ìjọba Ọlọrun mọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé, “Ìwọ fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.”