Jak 2:6-8
Jak 2:6-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ẹnyin ti bù talakà kù. Awọn ọlọrọ̀ kò ha npọ́n nyin loju, nwọn kò ha si nwọ́ nyin lọ si ile ẹjọ? Nwọn kò ha nsọ ọrọ-odi si orukọ rere nì ti a fi npè nyin? Ṣugbọn bi ẹnyin ba nmu olú ofin nì ṣẹ gẹgẹ bi iwe-mimọ́, eyini ni, Iwọ fẹ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ, ẹnyin nṣe daradara.
Jak 2:6-8 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ẹ̀ ń kẹ́gàn mẹ̀kúnnù. Ṣebí àwọn ọlọ́rọ̀ níí máa fìtínà yín, tí wọn máa ń fà yín lọ sí kóòtù! Ṣebí àwọn ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí orúkọ rere tí a fi ń pè yín! Ẹ̀ ń ṣe dáradára tí ẹ bá pa òfin ìjọba Ọlọrun mọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé, “Ìwọ fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.”
Jak 2:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu tálákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́? Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí? Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń mú olú òfin nì ṣẹ gẹ́gẹ́ bí Ìwé mímọ́, èyí tí ó wí pé, “Ìwọ fẹ́ ẹni kejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ,” ẹ̀yin ń ṣe dáradára.