Ó ṣe fún Arieli, Jerusalẹmu, ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun!
Ìlú tí Dafidi pàgọ́ sí.
Ẹ ṣe ọdún kan tán, ẹ tún ṣe òmíràn sí i,
ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún ní gbogbo àkókò wọn.
Sibẹsibẹ n óo mú ìpọ́njú bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun.
Ìkérora ati ìpohùnréré ẹkún yóo wà ninu rẹ̀,
bíi Arieli ni yóo sì rí sí mi.
N óo jẹ́ kí ogun dó tì yín yíká
n óo fi àwọn ilé ìṣọ́ ka yín mọ́;
n óo sì mọ òkítì sára odi yín.
Ninu ọ̀gbun ilẹ̀ ni a óo ti máa gbóhùn rẹ̀,
láti inú erùpẹ̀ ni a óo ti máa gbọ́, tí yóo máa sọ̀rọ̀.
A óo máa gbọ́ ohùn rẹ̀ láti inú ilẹ̀ bí ohùn òkú,
a óo sì máa gbọ́ tí yóo máa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ láti inú erùpẹ̀.
Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo pọ̀ bí iyanrìn,
ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìláàánú yóo bò ọ́ bí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.
Lójijì, kíá,
OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dé ba yín,
pẹlu ààrá, ati ìdágìrì, ati ariwo ńlá;
ati ààjà, ati ìjì líle,
ati ahọ́n iná ajónirun.
Ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun jà,
yóo parẹ́ bí àlá,
gbogbo àwọn tí ń bá ìlú olódi rẹ jà,
tí wọn ń ni í lára yóo parẹ́ bí ìran òru.
Bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa bá lá àlá pé òun ń jẹun,
tí ó jí, tí ó rí i pé ebi sì tún pa òun,
tabi tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ́ lá àlá
pé òun ń mu omi
ṣugbọn tí ó jí, tí ó rí i pé òùngbẹ ṣì ń gbẹ òun,
bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ogunlọ́gọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá Jerusalẹmu jà.
Ẹ sọ ara yín di òmùgọ̀,
kí ẹ sì máa ṣe bí òmùgọ̀.
Ẹ fọ́ ara yín lójú
kí ẹ sì di afọ́jú.
Ẹ mu àmuyó, ṣugbọn kì í ṣe ọtí.
Ẹ máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láì mu ọtí líle.
Nítorí OLUWA ti fi ẹ̀mí oorun àsùnwọra si yín lára
Ó ti di ẹ̀yin wolii lójú;
ó ti bo orí ẹ̀yin aríran.
Gbogbo ìran yìí sì ru yín lójú,
bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a fi èdìdì dì.
Nígbà tí wọ́n gbé e fún ọ̀mọ̀wé
tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.”
Ó ní òun kò lè kà á
nítorí pé wọ́n ti fi èdìdì dì í.
Nígbà tí wọ́n gbé e fún ẹni tí kò mọ̀wé
tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.”
Ó ní òun kò mọ̀wé kà.