HEBERU 13:7-16

HEBERU 13:7-16 YCE

Ẹ ranti àwọn aṣiwaju yín, àwọn tí wọ́n mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá fun yín. Ẹ ronú nípa iṣẹ́ wọn ati bí wọ́n ṣe kú. Kí ẹ ṣe àfarawé igbagbọ wọn. Bákan náà ni Jesu Kristi wà lánàá, lónìí ati títí lae. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àjèjì mu yín ṣìnà. Ohun tí ó dára ni pé kí ọkàn yín gba agbára nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun, kì í ṣe nípa ìlànà ohun tí a jẹ, tabi ohun tí a kò jẹ, irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kò ṣe àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ní anfaani. A ní pẹpẹ ìrúbọ kan tí àwọn alufaa tí wọn ń sìn ninu àgọ́ ti ayé kò ní àṣẹ láti jẹ ninu ẹbọ rẹ̀. Nítorí nígbà tí Olórí Alufaa bá wọ Ibi Mímọ́ lọ, wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹranko rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn sísun ni wọ́n ń sun ẹran ẹbọ wọnyi lẹ́yìn ibùdó. Bákan náà ni Jesu, ó jìyà lẹ́yìn odi ìlú kí ó lè sọ àwọn eniyan di mímọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkararẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí á gba irú ẹ̀gàn tí ó gbà. Nítorí a kò ní ìlú tí yóo wà títí níhìn-ín, ṣugbọn à ń retí èyí tí ó ń bọ̀! Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa rú ẹbọ ìsìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo nípasẹ̀ Jesu. Èyí ni ohun tí ó yẹ gbogbo ẹni tí ó bá ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa fún àwọn ẹlòmíràn ninu àwọn ohun ìní yín. Irú ẹbọ yìí ni inú Ọlọrun dùn sí.