← Àwon ètò
Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Heb 13:7

Àyànfẹ́ Ni Ọ́
Ọjọ́ Mẹ́rìn
Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ. Ẹnikẹ́ni tí o kò báà jẹ́, ipele tó wù kí o gbé wà ní ìgbésí ayé rẹ, Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ! Nínú oṣù yí, nígbà tí a bá ńṣe àjọyọ̀ ìfẹ́, má gbàgbé pé ìfẹ́ Ọlọ́run sí ọ ju gbogbo ìfẹ́ tó kù lọ. Nínú ẹ̀kọ́ ẹlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí, ri ara rẹ bọ inú ìfẹ́ Ọlọ́run.

Bíbélì Wà Láàyè
Ọjọ́ Méje
Ní àtètèkọ́ṣe, ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń mú ọkàn àti ẹ̀mí àwọn ènìyàn bọ̀sípò—Ọlọ́run ò sì tíì parí iṣẹ́. Nínú Ètò pàtàkì ọlọ́jọ́-méje yìí, ẹ jẹ́ kí a ṣe àjọyọ̀ agbára Ìwé Mímọ́ tó ń yí ìgbé-ayé ẹni padà nípasẹ̀ ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà lo Bíbélì láti yí àkọsílẹ̀-ìtàn padà àti láti mú àyípadà dé bá ìgbésí ayé àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé.