Ẹ̀yin ará Galatia, ẹ mà kúkú gọ̀ o! Ta ni ń dì yín rí? Ẹ̀yin tí a gbé Jesu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu sí níwájú gbangba! Nǹkankan péré ni mo fẹ́ bi yín: ṣé nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ fi gba Ẹ̀mí ni tabi nípa ìgbọràn igbagbọ? Àṣé ẹ ṣiwèrè tóbẹ́ẹ̀! Ẹ bẹ̀rẹ̀ pẹlu nǹkan ti ẹ̀mí, ẹ wá fẹ́ fi nǹkan ti ara parí! Gbogbo ìyà tí ẹ ti jẹ á wá jẹ́ lásán? Kò lè jẹ́ lásán! Ṣé nítorí pé ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ òfin ni ẹni tí ó fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fun yín ṣe fun yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí ó tún ṣiṣẹ́ ìyanu láàrin yín, tabi nítorí pé ẹ gbọ́ ìyìn rere, ẹ sì gbà á? Bí Abrahamu ti gba Ọlọrun gbọ́, tí Ọlọrun wá gbà á gẹ́gẹ́ bí olódodo, kí ó ye yín pé àwọn ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ni ọmọ Abrahamu. Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun yóo fi dá àwọn tí kì í ṣe Juu láre, ó waasu ìyìn rere fún Abrahamu pé, “Gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo di ẹni ibukun nípasẹ̀ rẹ.” Èyí ni pé àwọn tí ó gbàgbọ́ rí ibukun gbà, bí Abrahamu ti rí ibukun gbà nítorí pé ó gbàgbọ́.
Kà GALATIA 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: GALATIA 3:1-9
7 Awọn ọjọ
Gbogbo eniyan ni afi fún lati de ipò ìdáláre, tá owá ni àlàáfíà pẹlu Ọlọrun ati ará wa, nínú ìmọ pé Ọlọrun ti dariji ọ ati pé otí pa gbogbo ifisun rẹ àti ìdálẹbi rẹ rẹ́, kó ni óhùn kán sí ọ ṣugbọn O ri ọ gẹgẹbi òdodo Rẹ, O fẹràn rẹ, òsì ni ọpọlọpọ ileri ti O fi pámọ́ fún ọ. Ìgbé ayé ìyanu ni eyi jẹ! Ṣugbọn kini a nilo lati lè gbé igbeaye yii tabi ṣe oṣe ṣe?
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò