Gal 3:1-9

Gal 3:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ̀yin aláìnírònú ará Galatia! Ta ní ha tàn yín jẹ, kí ẹ̀yin má ṣe gba òtítọ́ gbọ́? Ní ojú ẹni tí a fi Jesu Kristi hàn gbangba láàrín yín ni ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Kìkì èyí ni mo fẹ́ béèrè lọ́wọ́ yín: Nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ̀yin gba Ẹ̀mí bí, tàbí nípa ìgbọ́ràn pẹ̀lú ìgbàgbọ́? Báyìí ni ẹ̀yin ṣe jẹ òmùgọ̀ tó bí? Ẹ̀yin tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ìgbàgbọ́ yín nípa ti Ẹ̀mí, ṣé a ti wá sọ yín di pípé nípa ti ara ni? Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán? Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ lásán ni. Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ́ sí ohun tí ẹ gbọ́? Gẹ́gẹ́ bí Abrahamu “Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.” Ẹ jẹ́ kí ó yé é yín nígbà náà pé, àwọn ti ó gbàgbọ́, àwọn náà ní í ṣe ọmọ Abrahamu. Bí ìwé mímọ́ sì tí wí tẹ́lẹ̀ pé, Ọlọ́run yóò dá aláìkọlà láre nípa ìgbàgbọ́, ó tí wàásù ìhìnrere ṣáájú fún Abrahamu, ó ń wí pé, “Nínú rẹ̀ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn tí i ṣe tí ìgbàgbọ́ jẹ́ ẹni alábùkún fún pẹ̀lú Abrahamu olódodo.