ISIKIẸLI 14:1-3

ISIKIẸLI 14:1-3 YCE

Àwọn àgbààgbà Israẹli kan tọ̀ mí wá, wọ́n jókòó siwaju mi. OLUWA bá bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọkunrin wọnyi kó oriṣa wọn lé ọkàn, wọ́n sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju wọn. Ṣé wọ́n rò pé n óo dá wọn lóhùn tí wọ́n bá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi?