Esek 14:1-3
Esek 14:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN kan ninu awọn àgba Israeli si wá sọdọ mi, nwọn si joko niwaju mi. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, awọn ọkunrin wọnyi ti gbe oriṣa wọn si ọkàn wọn, nwọn si fi ohun ìdigbolu aiṣedede wọn siwaju wọn: emi o ha jẹ ki nwọn bere lọwọ mi rara bi?
Esek 14:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn àgbààgbà Israẹli kan tọ̀ mí wá, wọ́n jókòó siwaju mi. OLUWA bá bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọkunrin wọnyi kó oriṣa wọn lé ọkàn, wọ́n sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju wọn. Ṣé wọ́n rò pé n óo dá wọn lóhùn tí wọ́n bá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi?
Esek 14:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Díẹ̀ nínú àwọn àgbàgbà Israẹli wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì jókòó níwájú mi, Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mí wá: “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti gbé òrìṣà kalẹ̀ sínú ọkàn wọn, wọ́n sì gbé àwọn ohun tó lè mú wọn ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú wọn; Èmi yóò ha jẹ́ kí wọ́n béèrè lọ́wọ́ mi rárá bí? Nítorí náà, sọ fún wọn pé