ẸKISODU 14:3-4

ẸKISODU 14:3-4 YCE

Nítorí Farao yóo wí pé, ‘Ilẹ̀ ti ká àwọn eniyan Israẹli mọ́, aṣálẹ̀ sì ti sé wọn mọ́.’ N óo tún mú kí ọkàn Farao le, yóo lépa yín, n óo sì gba ògo lórí Farao ati ogun rẹ̀, àwọn ará Ijipti yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bí OLUWA ti wí.