Eks 14:3-4
Eks 14:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoriti Farao yio wi niti awọn ọmọ Israeli pe, Nwọn há ni ilẹ na, ijù na sé wọn mọ́. Emi o si mu àiya Farao le, ti yio fi lepa wọn; a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori ogun rẹ̀ gbogbo; ki awọn ara Egipti ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA. Nwọn si ṣe bẹ̃.
Eks 14:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí Farao yóo wí pé, ‘Ilẹ̀ ti ká àwọn eniyan Israẹli mọ́, aṣálẹ̀ sì ti sé wọn mọ́.’ N óo tún mú kí ọkàn Farao le, yóo lépa yín, n óo sì gba ògo lórí Farao ati ogun rẹ̀, àwọn ará Ijipti yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bí OLUWA ti wí.
Eks 14:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Farao yóò ronú pé àwọn ọmọ Israẹli ń ráre káàkiri ní ìdààmú ni àti wí pé aginjù náà ti sé wọn mọ́. Èmi yóò sé ọkàn Farao le ti yóò fi lépa wọn. Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpàṣẹ Farao àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé èmi ni OLúWA.” Àwọn Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀.