Báyìí ni gbogbo wa yóo fi dé ìṣọ̀kan ninu igbagbọ ati ìmọ̀ Ọmọ Ọlọrun, tí a óo fi di géńdé, tí a óo fi dàgbà bí Kristi ti dàgbà. A kì í tún ṣe ọmọ-ọwọ́ mọ́, tí ìgbì yóo máa bì sọ́tùn-ún, sósì, tabi tí afẹ́fẹ́ oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àrékérekè àwọn tí wọn ń lo ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ láti fi tan eniyan jẹ yóo máa fẹ́ káàkiri. Ṣugbọn a óo máa sọ òtítọ́ pẹlu ìfẹ́, a óo máa dàgbà ninu rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, ninu Kristi tíí ṣe orí.
Kà EFESU 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: EFESU 4:13-15
3 Awọn ọjọ
Kìí ṣe pé ìgbé ayé onígbàgbọ́ ní ọ̀nà kan pàtó tí ó ń gbà ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti gba Krístì. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ ti Krístì, a ṣì wà nínú ayé yìí (Jòhánù 17:16). ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àlàkalẹ̀ nílò ìmúyàtọ̀ tí ó mú ìdọ́gba bá wíwà wa lójúkorojú nínú ayé pẹ̀lú ìdámọ̀ wa nípa ẹ̀mí. Bíi ẹ̀dá ti ẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ ṣe bó ti tọ́.
5 Awọn ọjọ
A pè wá sí iṣẹ́ aṣíwájú bíi Jesu. Iṣẹ́ aṣíwájú bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ara-ẹni, kìí ṣe ipò, ibi-àfẹ́dé Iṣẹ́ aṣíwájú sì jẹmọ́ ìdarí àwọn ènìyàn Ọlọrun sí ìpinnu Rẹ̀ fún ayé wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀kọ́-kíkà ojoojúmọ́ yìí yóò ṣèrànwọ́ láti ṣàgbékalẹ̀ ìpìlẹ̀ fífẹsẹ̀mulẹ̀ nípa ipò aṣíwájú tó ńránnilétí pé, kí o tó jẹ́ aṣíwájú, o kọ́kọ́ jẹ́ ìránṣẹ́, kí o tó jẹ́ ìránṣẹ́, o kọ́kọ́ jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ-Ọlọrun
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò