AMOSI 8
8
Ìran Nípa Agbọ̀n Èso
1OLUWA Ọlọrun, tún fi ìran mìíràn hàn mí. Lójú ìran, mo rí agbọ̀n èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kan. 2OLUWA bèèrè pé, “Amosi, kí ni ò ń wò yìí?” Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ni.” OLUWA bá sọ pé: “Òpin ti dé sí Israẹli, àwọn eniyan mi, n kò sì ní fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́. 3Nígbà tó bá yá, orin inú tẹmpili yóo di ẹkún, òkú yóo sùn lọ kítikìti níbi gbogbo, a óo kó wọn dà síta ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Ìparun Israẹli
4Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rẹ́ àwọn aláìní jẹ, tí ẹ múra láti pa àwọn talaka run lórí ilẹ̀ patapata. 5Ẹ̀ ń sọ pé: “Nígbà wo ni ìsinmi oṣù titun yóo parí, kí á lè rí ààyè ta ọkà wa? Nígbà wo sì ni ọjọ́ ìsinmi yóo kọjá, kí á lè rí ààyè ta alikama, kí á lè gbówó lé ọjà wa, kí á sì lo òṣùnwọ̀n èké, láti rẹ́ àwọn oníbàárà wa jẹ; 6kí á lè fi fadaka ra talaka, kí á lè ta aláìní, kí á sì fi owó rẹ̀ ra bàtà, kí á sì ta alikama tí kò dára?”
7OLUWA ti fi ògo Jakọbu búra; ó ní, “Dájúdájú n kò ní gbàgbé ẹyọ kan ninu iṣẹ́ ọwọ́ yín. 8Ǹjẹ́ kò yẹ kí ilẹ̀ náà mì tìtì nítorí ọ̀rọ̀ yìí kí àwọn eniyan tí ń gbé orí rẹ̀ sì máa ṣọ̀fọ̀? Gbogbo rẹ̀ yóo ru sókè bí odò Naili, yóo máa lọ sókè sódò, yóo sì fà bí odò Naili ti Ijipti. 9Ní ọjọ́ náà, n óo mú kí oòrùn wọ̀ ní ọjọ́kanrí, ilẹ̀ yóo sì ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan. 10N óo yí àsè àjọ̀dún yín pada sí ọ̀fọ̀, n óo sọ orin yín di ẹkún; n óo sán aṣọ ìbànújẹ́ mọ́ gbogbo yín nídìí, n óo sì mú kí orí gbogbo yín pá; ẹ óo dàbí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo, ọjọ́ náà yóo korò ju ewúro lọ.”
11OLUWA Ọlọrun ní, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo rán ìyàn sí ilẹ̀ náà; kì í ṣe ìyàn, oúnjẹ, tabi ti omi, ìran láti ọ̀dọ̀ OLUWA ni kò ní sí. 12Wọn yóo máa lọ káàkiri láti òkun dé òkun, láti ìhà àríwá sí ìhà ìlà oòrùn. Wọn yóo máa sá sókè sódò láti wá ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò ní rí i. 13Nígbà tó bá yá, àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn wundia yóo dákú nítorí òùngbẹ. 14Gbogbo àwọn tí wọn ń fi oriṣa Aṣima ti Samaria búra, tí wọn ń wí pé: ‘Bí oriṣa rẹ ti wà láàyè, ìwọ Dani,’ ati, ‘Bí ọ̀nà Beeriṣeba ti wà láàyè;’ gbogbo wọn yóo ṣubú, wọn kò sì ní dìde mọ́.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AMOSI 8: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010