TIMOTI KINNI 3:2-3

TIMOTI KINNI 3:2-3 YCE

Nítorí náà, olùdarí níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn; kò gbọdọ̀ ní ju iyawo kan lọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ọlọ́gbọ́n eniyan, ọmọlúwàbí, ẹni tí ó fẹ́ràn láti máa ṣe eniyan lálejò, tí ó sì fẹ́ràn iṣẹ́ olùkọ́ni. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí, tabi ẹni tí máa ń lu eniyan. Ṣugbọn kí ó jẹ́ onífaradà. Kò gbọdọ̀ jẹ́ alásọ̀, tabi ẹni tí ó ní ọ̀kánjúwà owó.