I. Tim 3:2-3
I. Tim 3:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ biṣopu jẹ alailẹgan, ọkọ aya kan, oluṣọra, alairekọja, oniwa yiyẹ, olufẹ alejò ṣiṣe, ẹniti o le ṣe olukọ. Ki o má jẹ ọmuti, tabi onijà, tabi olojukokoro, bikoṣe onisũru, ki o má jẹ onija, tabi olufẹ owo
I. Tim 3:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, olùdarí níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn; kò gbọdọ̀ ní ju iyawo kan lọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ọlọ́gbọ́n eniyan, ọmọlúwàbí, ẹni tí ó fẹ́ràn láti máa ṣe eniyan lálejò, tí ó sì fẹ́ràn iṣẹ́ olùkọ́ni. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí, tabi ẹni tí máa ń lu eniyan. Ṣugbọn kí ó jẹ́ onífaradà. Kò gbọdọ̀ jẹ́ alásọ̀, tabi ẹni tí ó ní ọ̀kánjúwà owó.
I. Tim 3:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ alábojútó yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùṣọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà rere, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́. Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí oníjàgídíjàgan, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó.