JOHANU KINNI 3:1-11

JOHANU KINNI 3:1-11 YCE

Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba fẹ́ wa tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọrun! Bẹ́ẹ̀ gan-an ni a sì jẹ́. Nítorí náà, ayé kò mọ̀ wá, nítorí wọn kò mọ Ọlọrun. Olùfẹ́, nisinsinyii ọmọ Ọlọrun ni wá. Ohun tí a óo dà kò ì tíì hàn sí wa. A mọ̀ pé nígbà tí Jesu Kristi bá yọ, bí ó ti rí ni àwa náà yóo rí, nítorí a óo rí i gẹ́gẹ́ bí ó ti rí. Gbogbo ẹni tí ó bá ní ìrètí yìí ninu Jesu yóo wẹ ara rẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Jesu fúnrarẹ̀, ti jẹ́ mímọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀ ń rú òfin, nítorí rírú òfin ni ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ sì mọ̀ pé Jesu wá láti kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun alára kò dá ẹyọ ẹ̀ṣẹ̀ kan. Gbogbo ẹni tí ó bá ń gbé inú rẹ̀ kò ní máa dẹ́ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀ kò ì tíì rí i, kò sì tíì mọ̀ ọ́n. Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe òdodo ni olódodo, bí Jesu ti jẹ́ olódodo. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń hùwà ẹ̀ṣẹ̀, láti ọ̀dọ̀ Èṣù ni ó ti wá, nítorí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé ni Èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọrun ṣe wá, kí ó lè pa àwọn iṣẹ́ Èṣù run. Gbogbo ẹni tí a bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun kò ní máa dẹ́ṣẹ̀ nítorí irú-ọmọ Ọlọrun yóo máa gbé inú olúwarẹ̀, nítorí náà, kò ní máa dẹ́ṣẹ̀ nítorí a bí i láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Ọ̀nà tí a fi lè mọ àwọn ọmọ Ọlọrun yàtọ̀ sí àwọn ọmọ Èṣù nìyí: gbogbo ẹni tí kò bá ṣe iṣẹ́ òdodo tí kò sì fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ kò wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ara wa.